Màá ríi dájú pé iná mọ̀nàmọ́ná kò ṣẹ́jú ní Ogun kí n tó kúrò ní ìjọba - Dapo Abiodun

Aworan Gomina Ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Facebook/DapoAbiodunorg

Gomina Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun ti ni oun yoo sa akitiyan lati ri pe isoro ina mọnamọna dopin ki oun to kuro ni isejọba gẹgẹ bi Gomina.

Abiodun, ẹni ti ile ẹjọ kotẹmilọrun kede pe oun lo jawe olubori ninu eto idibo Gomina to kọja, sọ fun ileeṣẹ Channels TV pe oun setan lati se ju bi oun sese tẹlẹ lọ nipinlẹ.

"Erongba mi fun ọdun mẹrin saa keji yii ni lati ri pe ina mọnamọna ko sẹju mọ nipinlẹ Ogun kí n to kuro ni isejọba."

Gẹgẹ bii o se salaye oun ni ijọba oun yo bẹrẹ si ni ma tun awọn ile ẹkọ ijọba fun igbaladun awọn akẹkọọ kaakiri ipinlẹ.

"O to ẹgbẹrun kan ile ẹkọ ti a ti tun kọ, ti a dẹ tun se atunse si wọn laarin ọdun mẹrin."

O fikun pe isejọba oun ti ṣe atunse awọn oju popona, kikọ ile iwosan ati pipese isẹ fun awọn ọdọ.

Bakan naa Gomina tun fi ogun rẹ gbari pe ipinlẹ Ogun le da duro lai gba owo lọwọ ijọba apapọ nitori bí ọrọ aje ṣe n gboro si ipinlẹ naa.

"O da mi loju pe ẹ mọ pe ipinlẹ Ogun lo n lewaju nínu awọn ipinlẹ tí ilọsiwaju ba eto ọrọ aje wọn.