A ò lè máa wòrán láì ní gómìnà l'Ondo - PDP fọnmú, kò sí èrò láti sọ Aiyedatiwa di adelé gómìnà - Ilé aṣòfin fèsì

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, Kennedy Peretei, ti ke si ile aṣofin ipinlẹ naa lati sọ igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa di adele gomina.
Peretei lo wi pe ija ti Aarẹ Bola Tinubu pari laarin awọn igun mejeeji to n ṣe faakaja lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa ko yanju aawọ to wa nilẹ.
Peretei ṣalaye fun akọroyin BBC News Yoruba pe oun ko ri ohun kan to yanju ninu aawọ naa abi anfani to ṣe fun awọn olugbe ipinlẹ Ondo.
O ni ipinlẹ Ondo ni ko lee tẹsiwaju lai si ẹni to n dari ijọba to si n ṣe ojuṣe gomina.
Peretei wi pe Aiyedatiwa lo yẹ ki wọn sọ di adele gomina latari ailera gomina ti araalu jọ fibo gbe wọn sipo.
Peretei wi pe “igun Ayedatiwa n yọ pe ko sogun iyọnipo lọrọ ọga awọn mọ, bẹẹ lawọn igun keji ti wọn ni wọn wa lẹyin gomina Akeredolu naa n yọ pe oun ṣi ni gomina.
"Akeredolu ti aarẹ si ni ko maa tẹsiwaju bii gomina ni ko ti ẹ le e yọju sibi ipade ti wọn ṣe ọhun.
"Bi Akeredolu ko ṣe le yọju sibi ipade ti aarẹ pe yii tunmọ si pe ọkunrin naa ko tii gbadun, eyi si n mu mi beere boya o le tẹsiwaju bii gomina.”
Tani yoo maa ṣoju ipinlẹ Ondo nibi ipade aarẹ atawọn gomina?
Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa tẹsiwaju pe awọn ko le sọ ni pato pe ọwọ ẹnikan bayii ni akoso ijọba ipinlẹ Ondo wa bayii.
"Tani ki a di ẹbi aiṣedeede ijọba yii ru abi ki a gbe oriyin fun ti ijọba yii ba ṣe ohun to wuyi?
"Njẹ Aiyedatiwa le lọ ṣoju ipinlẹ yii nilu Abuja nibi ipade igbimọ to n moju ọrọ-aje orilẹ-ede yii?
Ṣe Aiyedatiwa ni yoo maa dari ijọba ni abi agbarijọ awọn kan ni gẹgẹ bi aarẹ ṣe yanju ẹ fun wọn?
Ohun ti mo mọ ni pe, bi Akeredolu ko ba wale lati waa bẹrẹ iṣẹ rẹ pada bii gomina, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ laarin wọn ni.
Ohun kan ṣoṣo to le yanju aawọ yii ni ki wọn sọ Aiyedatiwa di adele gomina, ko si maa dari ijọba titi di igba ti ọga rẹ yoo pada de," Peretei sọ.
Ko si igbiyanju kankan lati sọ Aiyedatiwa di adele gomina
Ẹwẹ, adari ọmọ-ile to pọju lọ nile aṣofin ipinlẹ Ondo, Oluwole Ogunmolasuyi ti ni ko si nkankan to jọ pe wọn fẹ sọ igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa, di adele gomina.
Lakooko to n fesi si ibeere akọroyin BBC News Yoruba lori abajade ipade ti wọn ṣe pẹlu Aarẹ Tinubu, Ogunmolasuyi wi pe, ohun ti gbogbo wọn fẹnu ko si ni lati gba alaafia laaye.
Aṣofin naa wi pe “n ko mọ nkankan nipa pe wọn fẹẹ fi igbakeji gomina ṣe adele gomina. Ko si eleyii ninu afẹnukosi wa”.
Ogunmolasuyi to wa lati ilu kan naa pelu gomina Akeredolu fi kun pe ki onikaluku tẹsiwaju laaye to wa, ko ma si si wahala kankan mọ ni abajade ipade naa.
Eyi ti ẹ lọ ṣe l'Abuja o kan wa, ẹ tẹle ofin lati sọ Aiyedatiwa di adele gomina — Awọn igun kan ni APC
Awọn agbaagba kan lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo ti wọn pera wọn ni APC Progressives Stakeholders lo ti bu ẹnu atẹ lu ipade ipẹtusaawọ to waye nilu Abuja.
Ninu atẹjade kan ti alaga agbarijọ awọn eekan ẹgbẹ APC ọhun, Afe Olowookere, to figba kan ri jẹ ọmọ ile aṣojuṣofin l'Abuja, ati akọwe wọn, Raman Rotimi, toun naa ti ṣe akọwe ẹgbẹ APC nipinlẹ naa ri, ni wọn ti wi pe o ṣe pataki ki igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa, o di adele gomina ni kiakia.
Wọn wi pe aisi nile Gomina Oluwarotimi Akeredolu lo ti ṣe akoba gidi fun ọrọ-aje ipinlẹ naa.
Atẹjade naa to ṣe atẹnumọ ki ile aṣofin ipinlẹ naa o sọ Aiyedatiwa di adele gomina lọgan, wi pe “o yẹ ki wọn fun awa ọmọ ẹgbẹ laaye lati le yan awọn taa fẹ ko dipo oṣelu mu.
“O yẹ ki awọn agba ẹgbẹ ni apọnle ninu ẹgbẹ ki wọn si lee da si ọrọ dipo ki wọn maa gbe nkan gba ẹyin wọn.”















