Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n fi Oranmiyan tí ìlú Oko sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo?

Oba Solomon Akinola

Oríṣun àwòrán, From the Palace of Oranmiyan of Oko Land/FACEBOOK

Oranmiyan ti ìlú Oko, ìjọba ìbílẹ̀ Surulere, ìpínlẹ̀ Oyo, Ọba Olagoke Solomon Akinola ti ní kò sí ilé ẹjọ́ kankan tó fi òun àtàwọn ènìyàn mẹ́rìnlá míì sí àhámọ́ kankan.

Oba aláyé náà sọ àfọ̀mọ̀ ọ̀rọ̀ ọ̀hún nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo lópin ọ̀sẹ̀.

Oranmiyan ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ ilẹ̀ lọ ṣokùnfà ìfaǹfa èyí tí wọ́n ti wà lẹ́nu lọ́jọ́ pípẹ́ tó sì ṣokùnfà ìdí tí àwọn fi fojú ba ilé ẹjọ́.

Ṣáájú ni àwọn ìròyìn kan jáde lọ́sẹ̀ tó kọjá pé ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo tó fi ìlú Ogbomoso ṣe ibùjókòó ti fi Ọba Akinola sí àhámọ́.

Ìròyìn náà ní Ọba Akinola àtàwọn mẹ́rìnlá míì ni ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n lọ fi sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo fún ìgbà kan ná fẹ̀sùn wí pé wọ́n ṣe ìkọlù sí ẹnìkan lọ́nà àìtọ́.

Wọ́n ní Adájọ́ Adedokun ló pàṣẹ náà nígbà tí Dókítà Isaac Abiodun kan mú ẹjọ́ wọn wá pé wọ́n fìyà jẹ òun lọ́nà àìtọ́ ní abúlé Aagba.

Adájọ́ Adedokun lòdì sí ìkọlù náà, tó sì ní kí wọ́n lọ fi ọba náà àti àwọn èèyàn rẹ̀ sí àhámọ́ nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ìkìlọ̀ ilé ẹjọ́ láti gba àláfíà láàyè gẹ́gẹ́ bí ilé ẹjọ́ ṣe sọ fún wọn nígbà tí ẹjọ́ náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Kẹrìndínlọgún oṣù Kọkànlá ọdún 2023.

Ẹ̀wẹ̀, Ọba náà tí wá sọ̀rọ̀ pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà pé lóòótọ́ ni àwọn lọ sílé ẹjọ́ lọ́jọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kọkànlá ọdún 2023 àmọ́ adájọ́ kò fi òun sí àhámọ́ rárá.

Ó ṣàlàyé nígbà tí àwọn dé ilé ẹjọ́, adájọ́ ní kí òun tọwọ́ bọ̀wé pé òun máa ma mú àwọn ènìyàn òun tí àwọn jọ ń jẹ́jọ́ wá sílé ẹjọ́ ní gbogbo ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ yóò bá wáyé tí òun sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó ní adájọ́ kò ti ẹ̀ bèèrè onídùróó lọ́wọ́ òun nítorí ọba onípò kìíní tí òun jẹ́ àti ipò òun láwùjọ.

Kí ló fa wàhálà tó sọ Oranmiyan di ẹni tó ń paààrà ilé ẹjọ́?

Oba Solomon Akinola

Oríṣun àwòrán, From the Palace of Oranmiyan of Oko Land/FACEBOOK

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹ́gẹ́ bí Oba náà ṣe sọ, ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ló gbé wọn dé ilé ẹjọ́.

Oba Solomon Akinola ní láti bí ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún (93) ni àwọn ti wà lórí ọ̀rọ̀ náà àti pé onírúurú ìdájọ́ ló ti wáyé lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà ti dé ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ìyẹn Supreme court àti pé wọ́n ti mú ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí ìdájọ́ máa wáyé lórí rẹ̀.

Ó ní lọ́dún 2021 ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí Abuja tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn ìgbéṣùmọ̀mí kan àwọn àtàwọn ẹ̀sùn míì kí wọ́n tó dá àwọn ènìyàn padà sí ìpínlẹ̀ Oyo lẹ́yìn tí wọ́n lo ọdún kan àti bíi oṣù mẹ́wàá ní àhámọ́ Abuja àti Ibadan.

Ó fi kun pé lọ́jọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni wọ́n tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ tí àwọn sì ti ń retì láti gbọ́ láti ilé ẹjọ́ àma tí àwọn kò gbọ́ nǹkankan mọ́.

Oba tẹ̀síwájú pé ní ìparí oṣù Kẹwàá ni agbẹjọ́rò òun kàn sí òun pé tí tún fi àwọn ẹ̀sùn mìíràn kan àwọn, tí àwọn sì lọ sílé ọjọ́ lọ́ja Keje oṣù Kọkànlá tí a sì sọ fún adájọ́ pé a ò rí ìwé ẹ̀sùn kankan gbà.

“Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kọkànlá ọdún ni a tún lọ sílé ẹjọ́, tí a sì jìyàn gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá, adájọ́ ní kí n gba béèlì ara mi nítorí ọba onípò kìíní tí mo jẹ́.

“Ní ọjọ́ Kọkànlélógún ni a tún padà sílé ẹjọ́ tí adájọ́ sì gbà béèlì mi àtàwọn èèyàn mi wọlé, pé kí n máa ri dájú pé wọ́n ń wá sílé ẹjọ́ ní gbogbo ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ bá ti wà.

“Ó yà mí lẹ́nu pẹ̀lú gbogbo ìròyìn tí mò ń kà lórí ayélujára pé wọ́n fi wá sí àhámọ́.”

Ó ní ìgbìmọ̀ láti ba òun lórúkọ jẹ́ ni àwọn ìròyìn tí àwọn kan ń gbé kiri náà.