Wákàtí diẹ ló kù tí Christopher Olusa, akẹ́kọ̀ọ́ tó n gbìyànju GWR ọ̀rọ̀ sísọ tó pẹ́ jùlọ yóò fí fí ìtàn lé lẹ̀

Àkọlé fídíò, GWR: Ẹ wo bí Akẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe fí ìtàn lé lẹ fún sísọ ọ̀rọ̀ tó pẹ julọ

Akẹkọọkunrin ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan Christopher Olusa ti n sunmọ ko fi orukọ lelẹ ninu iwe itan Guiness World Record gẹgẹ bi ẹni to sọrọ fun wakati to pẹju lọ.

Lasiko taa n ṣe akojọ iroyin yi o ti kọja wakati mẹtalelọgọrun to si ku nkan bi wakati mẹtadinlogun ti yoo fi de afojusun wakati ọgọfa to n gbiyanju lati de.

Ọjọ marun un lo yan lati fi pa itu yi to si bẹrẹ ni ọjọ kọkanla oṣu Kẹsan ọdun yi ni ile itura Dejavu nilu Akure.

Ẹni to fi orukọ lelẹ ninu itan ṣaaju asiko yi da ọrọ sọ fun aadọrun wakati ati iṣẹju meji.

Lọwọ bayii, Christopher ti kọja iye wakati ti ọmọ orileede Nepal Nepal Ananta Ram KC fi da ọrọ sọ.

Afihan igbiyanju yi n waye ni oju opo Facebook bo ṣe n lọ lọwọ.

Ninu fọnran fidio taa ri Christopher wea lori pẹpẹ nibi to ti n sọrọ.

Loore koore awọn to peju sibi eto naa n beere ọrọ ti Christopher a si maa da wọn lohun nipa idahun si ibeere wọn yi.

Aworan Christopher nibi to ti n sọrọ

Oríṣun àwòrán, DukeofAkoko

Ṣe GWR fọwọ si igbiyanju ọlọjọ marun un rẹ yi?

Nigba ti ọdọmọkunrin yi n ba awọn akọroyin sọrọ ṣaaju ko to bẹrẹ eto ''speak-a-thon '' yi, o ni inu oun dun pe ''igbiyanju wa ti so eso rere bay tori Guiness World Record ti fun wa ni iyọnda lati ṣe igbiyanju yi''

O tẹsiwaju pe oun yoo maa ka ninu apilẹkọ ọrọ bẹẹ loun yoo si maa dahun ibeere tawọn eeyan ba fi ṣọwọ.

O ṣalaye pe oun ṣe ipalẹmọ ati igbaradi lorisirisi ki oun baa le ni okun ati agbara iṣẹ to wa niwaju yi.

Ninu iwnba wakati diẹ taa wo ninu ọrọ sisọ rẹ, a ri to n dahun ibeere lori orisi ọrọ to fi mọ ibeere nipa oṣelu,ọrọ aje, ere idaraya ati ibeere nipa idagbasoke Naijiria lapapọ.

Koda ninu ọrọ to sọ la ti ri ibi to ti ka ọrọ idupẹ ti Aarẹ Tinubu ka lẹyin to jaweolubori lẹyin idibo aarẹ Naijiria ọdun 2023.

Aworan esi to jẹ gẹgẹ bi ẹri tori gba lọdọ GWR ko to le tẹsiwaju igbiyanju yi ree:

Aworan afihan esi ti GWR da pada fun Christopher Olusa

Oríṣun àwòrán, Christopher Olusa

Ọmọ Naijiria ati GWR

Lati igba ti Hilda Bacci ti gba ami ẹyẹ GWR fun ẹni to lo wakati to pọ julọ nidi ina dida ni igboro ti daru pẹlu gbogbo awọn nnkan ẹfẹ ti awọn eeyan ni awọn fẹ ṣe lati gba ami ẹyẹ.

Koda awọn oniṣẹ ọwọ biii onidiri, olounjẹ gan atawọn adẹrinpoṣonu ti ko wọ inu fifi ami ẹyẹ GWR yii ṣe ẹfẹ.

Eyi mu ki GWR ko awọn eeyan nijanu diẹ ti wọn si ni ẹni ti yoo ba ṣe igbiyanju kankan ti yoo jẹ manigbagbe gbọdọ kọwe si awọn fun iyọnda ki wahala wn ma ba ja sasan.

Lasiko yi ti Christopher n ṣe tiẹ lọwọ bakan naa la ri ti arakunrin ọmọ Naijiria mii ti gba ami GWR fun ẹni to lo wakati to pọju lati gun oke pẹlu bọọlu to gbe sori gẹngẹ.

Tonye Solomon lorukọ arakunrin naa.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post