Mọ̀ síi nípa Ọkùnrin kan tó fẹ ìyàwó méje lẹ́ẹ̀kan náà

Oríṣun àwòrán, Tuko
Ssaalongo Nsikonenne Habib Ssezzigu ni ọrọ rẹ tí gba ori ayelujara lẹyin to fẹ iyawo meje ni ọjọ kan naa.
Lara obinrin meje ni a ti rí ẹgbọn ati abur, ti igbeyawo ọhun si waye ni Abule Bugerek lorilẹede Uganda lọjọ kẹwaa oṣu kẹsan an ọdun 2023.
Orukọ awọn iyawo naa ni Mariam, Madinah, Aisha, Zainabu, Fatuma, Rashida ati Musanyusa, to jẹ iyawo rẹ akọkọ to ti wa pẹlu rẹ fun ọdun meje.
Ninu atẹjade kan to wa lori ayelujara, sọrọ sọrọ Caleb Canaan ni ayẹyẹ igbeyawo bẹrẹ ni ago mẹjọ aarọ lẹyin ti wọn gbe awọn iyawo naa lọ ile oni diri.
"Lẹyin ọkọ ati awọn iyawo rẹ ṣe ibura, Nsikonenne ati awọn iyawo rẹ meje gun kẹkẹ kaakiri abule bí Kalagi, Kasana ati Nakifuma kí wọn to lọ ile wọn ni ago mẹfa irọlẹ."
Nsikonenne ra ọkọ bọgini tuntun fun awọn iyawo naa, to si rọ àwọn iyawo naa lati fẹ ẹ pẹlu otitọ inu.
"Ko si owu laarin awọn iyawo mi. Mo mọ wọn ní ọtọọtọ ti mo si pinnu lati fẹ ṣe igbeyawo pẹlu wọn ní ẹkana lati ni idile alayọ."
Nsikonenne ni oun yoo tun fẹ iyawo si lọjọ iwaju
"Ọmọde si ni mi ati pe lọjọ iwaju, ti Ọlọrun ba fẹ ma fẹ iyawo si."
Baba ọkọ, Hajj Abdul Ssemakula ni fifẹ iyawo pupọ lo jẹ nnkan to wa ninu ẹjẹ mọlẹbi wọn.
"Baba to bi baba mi fẹ mẹfa, Baba mi fẹ marun un, emi gan fẹ fẹ mẹrin ti a jọ n gbe ile kan naa."
Habib lo ti wa fi itan balẹ gẹgẹ ọkunrin to fẹ iyawo meje lẹẹkana lorilẹede Uganda.












