Wo bóyá ìpínlẹ̀ rẹ wà nínú àwọn 13 tí ìjọba ní kò múra dé òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá oṣù yìí

Aworan ile ti ojo ya de ẹnu ọna rẹ ni Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

E bẹrẹ si ni gbaradi fun arọrọda ojo to le ṣokunfa omiyale ni ilu mejidinlaadọta lawọn ijọba ipinlẹ mẹtala.

Ikilọ ree lati ọdọ ijọba apapọ Naijriia eyi ti wn ni yoo waye laarin ọjọ Kẹtala si ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹsan 2023.

Ninu ikede yi wọn sọ pe ẹkun omi lodo Niger ati Benue ṣeeṣe ko ṣakoba fawọn ileto to wa leti odo titi kan ipinlẹ Bayelsa.

Tori naa ijọba kilọ fawọn olugbe agbegbe wọnyi lati gbe awọn igbesẹ ipalẹmọ de arọrọda ojo yi.

Ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ayika ni o gbe ikede yi sita ninu abajade iwadii lori iṣẹlẹ omiyale ti wọn si fi iroyin yi ṣọwọ sawọn akọroyin.

Gẹgẹ bi abajade yi ṣe sọ,awọn ijọba ipinlẹ mẹtala ti ọrọ naa kan ni wọnyi Kano, Kebbi, Katsina, Niger, Kwara, Zamfara, Bauchi, Taraba, Borno, Adamawa, Yobe, Jigawa ati Gombe.

Abajade iwadii yi tẹsiwaju pe awọn wọnyi lagbagbe ti yoo koju arọrọda ojo lawọn ipinlẹ lasiko taa foju sun:“Ni Kano : ilu Sumaila ati Kunchi; Kebbi: Argungu; Katsina: Bindawa, Jibia, Kaita ati Katsina; Niger: Kontagora, Mashegu, New Bussa; ati Kwara,Kosubosu.”

Ni ipinlẹ miran bi Zamfara iwadii naa tọka si Kaura Namoda ati Shinkafi gẹgẹ bi ilu to le koju arọrọda ojo to le mu omiyale wa nigba ti Bauchi naa le ri iru arọrọda ojọ taa n wi yi ni awọn ilu Bajoga, Darazo, Kirfi, Azare, Jama‘are, Itas ati Misau.

Iṣẹlẹ arọrọda oṣu a maa waye ni awọn oṣu ipari ọdun nitori asiko yi lojo maa n pọ ju tatẹyinwa lọ.

Jakejado agbagbye bayi iyipada ojo ọjọ ti mu ki iṣọwọ bi ojo ṣe n rọ maa pọ juti tẹlẹ lọ.

Bi a ba ti n fọkan tẹle iroyin to n lọ lagbaye lasiko yi, a o ti maa gburo bi arọrọda ojo ati atẹgun lile ṣe ṣakoba fun ọpọ ẹmi ati dukia lorileede Libya.

Botilẹ jẹ wi pe Libya jina diẹ si Naijiria eyi n tọka si pe ki awọn eeyan orileede Naijiria naa ma fi ina sori orule sun lọ kete ti awọn alaṣẹ ba ti kede pe o ṣeeṣe ki wọn koju arọrọda ojo.