Ayẹyẹ gbígbé ọ̀pá àṣẹ fún Ọba Ghandi yóò tẹ̀síwájú -Amúgbálẹ́gbẹ̀ Soun sàlàyé

Aworan Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Prince Olaoye Afolabi Ghadi

Idajọ ile ẹjọ giga ilu Ogbomọṣọ to waye lọjọ Aje ṣebi ẹni n tọka si pe ayẹyẹ iwuye ati gbigbe ọpa aṣẹ le Soun Ogbomoso Ọba Ghandi Afolabi Olaoye Orunogege III, Soun ti ile Ogbomoso yoo tẹsiwaju.

Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Soun Peter Olaleye lo fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba to si ni eto gbigba ọpa aṣẹ yoo waye laisi idaduro kankan.

Inu oṣu Kejila ni wọn ti la kalẹ ninu eto pe ayẹyẹ gbigbe ọpa aṣẹ le Soun lọwọ yi yoo waye.

Wọn yoo ṣe ayẹyẹ naa laarin ọjọ Kẹrinla si ọjọ Kọkandilogun.

Wọn ti ṣaaju ṣe awọn eto iwuye mii ni ibamu aṣa ilu naa eyi ti wọn fi gbade le Ọba Ghandi lori amọ ni ti ayẹyẹ ti wọn yoo pe tonile talejo lati wa kopa ni ayẹyẹ gbigbe ọpa aṣẹ yi jẹ.

Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde si ni ẹni ti yoo gbe ọpa aṣẹ yi le Soun lọwọ.

Idajọ ti ijọba ipinlẹ gab dari lati ile ẹjọ ni pe ki Ọba Ghandi ṣ i wa lori oye gẹgẹ bi Soun.

Idajọ ileẹjọ to waye, bawo lọrọ ṣe ri

Awọn alatilẹyin Ọba Ghandi fi idunnu wọn han lẹyin ti ile ẹjọ Giga sọ pe ko tẹsiwaju lati maa dari ilu Ogbomoso gẹgẹ bi Soun.

Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni Adajọ K. A. Adedokun da ẹjọ naa laarin ọmọba Muhammed Olaoye ati ijọba ipinlẹ Oyo atawọn mọkanla mii, ninu eyii to ti ni kudiẹkudiẹ wa ninu iyansipo ọba Ghandi Olaoye, nitori naa ko fi ipo naa silẹ.

Bẹẹ ladajọ ọhun to sọ pe ki wọn tun eto iyanispo Ọba ọhun bẹrẹ lakọtun.

Idajọ yi jẹ ohun ti ko ba Gomina Seyi Makinde ati awọn mii lara mu.

Lẹyin idajọ ọhun ni Akin Onigbinde, SAN, pe ẹjọ kotẹmilọrun lorukọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn mii ti ọrọ naa kan ni atako idajọ to ni ki wọn gbade lori Ọba Ghandi.

Ki wọn to bẹrẹ si ni gbẹjọ kotẹmilọrun yi naa ni agbẹjọro Gomina ti tọrọ iyọnda lọdọ ileẹjọ lati dawọ yiyọ Soun duro ko si maa tẹsiwaju ipo rẹ titi ti wọn yoo fi pari ẹjọ kotẹmilọrun

Titi di asiko yi wọn ko ti pe ipẹjọ lori ẹjọ Kotẹmilọrun yi tabi kede ọjọ ti yoo bẹrẹ.

Nigba wo lọrọ awuyewuye yi yoo yanju?

Ko si ẹni le sọ pato ibi ti ọrọ awuyewuye lori ipo Soun yi yoo kangun si.

Lati ibẹrẹ pẹpẹ naa ni awọn ikunsinu ti wa tawọn kan ninu idile Laoye ti n fapajanu si si iyansipo Ọba Ghandi.

Ẹjọ kotẹmilọrun ti ijọba Oyo pe yi le gba asiko diẹ ki wọn to yanju rẹ to si n jọ pe Ọba Ghandi yoo ti gba ọpa aṣẹ ki wọn to gba idajọ lori rẹ.

Ibi ti idajọ yi yoo fi si ni a ko le sọ amọ bo ba gbe Ọba bi ko gbe e ilu Ogbomosho ko rebi kankan.

Kii ṣe nkan tuntun lati gbọ pe wọn ṣe fakinfa lori oye Ọba jijẹ yala ni ilẹ Yoruba tabi awn apa Naijiria mii.

Wọn o ṣẹṣẹ maa yọ Ọba ti wọn de ade fun lẹyin ọpọ ọdun ti ile ẹjọ ba sọ pe ipo naa ko tọ si i.

Koda nigba mii wn yoogbe ẹjọ naa de ile ẹjọ to gajulọ ki idajọ to waye lori ẹni ti ipo naa tọ si.