Ó ṣe! Baálé ilé kó sódò n'Ilorin, pàdánù ẹ̀mí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE
Nṣe ni ọkan awọn olugbe agbegbe Agba Dam ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara nigba ti wọn ṣadede ri oku ọkunrin kan ninu odo lagbegbe naa.
Ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni awon eeyan naa ri oku ọkunrin ọhun to lefoo lori odo nla Agba Dam.
Ohun to runi loju lori iṣẹlẹ ọhun ni wi pe, ko si ẹni to mọ ohun to mu baale ilé naa ti ọjọ ori rẹ yoo to bi ogoji ọdun ṣe de inu odo nla naa.
Bakan naa ni a o tii ri ẹni to mọ orukọ rẹ tabi molẹbi rẹ kankan titi di asiko ta a n ko iroyin yii jọ.
Ile iṣẹ panapana ipinlẹ Kwara ninu atẹjade kan to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ni awọn ara adugbo naa lo kan si awọn lati fẹjọ iṣẹlẹ naa ti awọn si lọ sibẹ lati lọ yọ oku ọhun.
Ọkunrin kan to n jẹ Onikẹpẹ Bọlaji, lo pe Ileeṣẹ panapana iluu Ilọrin ni ipe pajawiri, pe ọkunrin kan ti ko sodo to si ti mu omi yo bamu, ti wọn ko si mọ bi oloogbe naa ṣe de inu odo ọhun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni Kwara, Hassan Adekunle, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni awọn gba ipe pajawiri kan ni nnkan bii aago mọkanla ku iṣẹju mẹwaa aarọ lọjọ Aje, Mọnde, lati agbegbe Agbà-Dam, nijọba ibilẹ Ìlà-Oòrùn (Ilorin East).
O ni ohun ti wọn ba awọn sọ ni pe wọn ri ọkunrin kan ninu odo, tawọn si lọọ yọ ọ jade, ṣugbọn o ti mumi yo, to si ti ku kawọn to gunlẹ sibi iṣẹlẹ naa.
O tẹsiwaju pe ni kete tawọn yọ oku naa, tawọn ko mọ mọlẹbi rẹ kankan, awọn si gbe e le ọlọpaa DSP Achimugu, lọwọ loju-ẹṣẹ.
Ọga agba ajọ panapana Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, fi ibanujẹ ọkan rẹ han lori iṣẹlẹ naa, o rọ gbogbo olugbe ipinlẹ ọhun lati maa ṣọra gidigidi lori gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe lojoojumọ, ki wọn si maa takete sawọn eti odo lagbegbe wọn
Awọn ara agbegbe Agba Dam to ba BBC News Yoruba sọrọ lori niṣẹlẹ buruku yii, bẹbẹ ki a fi orukọ bo awọn lasiri.
Wọn ni arakunrin naa ko le jẹ olugbe agbegbe awọn nitori ko si ẹni to daa mọ ati pe awọn ko gbọ pe eeyan kankan sọnu ni adugbo awọn.
Wọn ni, o seese ko jẹ awọn ẹni ibi lo wa sọ oku rẹ sinu odo naa tabi ko se ohun gaan fun ra rẹ lo kan sodo, to si gbẹmi ara rẹ.
Bakan naa lo ṣeeṣe ko jẹ pe lati ọna jinjin rere kan ni oku ọkunrin naa ti ṣan wa si agbegbe naa.
Wọn fi kun un pe, ohun toju eniyan ko to, oju Ọlọrun too.















