Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìbò tó gbé gómìnà Kano wọlé, ó ní Guwana APC ló wọlé

Oríṣun àwòrán, NASIR GUWANA/ABBA KABIR YUSUF
Ileẹjọ kotẹmilọrun to n joko niluu Abuja wọgile ibo to gbe Gomina Abba Kabir Yusuf, ileẹjọ naa dajọ wi pe Nasiru Gawuna oludije ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle ibo ọhun.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun fontẹ lu idajọ igbimọ ẹlẹni mẹta to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina ninu eyi ti Adajọ Akintan Osadebay ti wọgile ibo to gbe Gomina Yusuf ni ogunjọ oṣu kẹsan an ọdun yii.
Ileẹjọ Triunal sọ ninu idajọ rẹ pe ibo 165,663 ti Yusuf ni lo jẹ ayederu nitori osisẹ ajọ eleto idibo INEC ko buwọlu iwe ibo naa.
Ajọ eleto idibo INEC kede Yusuf to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu NNPP gẹgẹ ni oludije to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Kano loṣu Kẹta pẹlu ibo 1,019,602 nigba ti ajọ naa ni ibo 890,705 ni Gawuna ni ninu ibo ọhun.
Ilẹ ẹjọ naa yọ ibo 165,663 kuro ninu gbogbo ibo ti Yusuf pẹlu alaye wi pe ko si ontẹ tabi ibuwọlu lori awọn ibo naa.
Gbogbo ẹsun mẹtẹẹta ti APC fi kan NNPP lori eto idibo ọjọ kọkanla oṣu Kẹta ni igbimọ igbẹjọ naa da APC lare lori wọn.
Lẹyin naa ni Yusu gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ nigba ti ko faramọ idajọ igbimọ to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina.
Bayii ni idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣe lọ
Ile ẹjọ kotẹmilọrun fidi rẹ mulẹ ninu idajọ rẹ pe Yusuf ko koju oṣunwọn lati dupo gomina Kano.
Igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta ti Adajọ M.A Adumeh dari wọn ni orukọ Yusuf ko si ninu iwe ọmọ ẹgbẹ osẹlu NNPP.
Adajọ Adumeh ni orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ gbọdọ wa ni akọsilẹ ninu iwe orukọ ẹgbẹ oṣelu kọọkan gẹgẹ bi ofin ṣe laa kalẹ.
O fikun un pe Yusuf gan an fun ra ko jiyan nigba ti wọn fẹsun kan an wi pe ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu NNPP, bẹẹ ni ko wi awijare kankan.
Adajọ Adumen ni ileẹjọ ko ni gba ẹgbẹ osẹlu kankan laaye lati ṣe ohun to ba wu wọn.
O ni ẹnikẹni to ba fẹ dupo oṣelu gbọdọ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan tabi omiiran, ati pe ẹgbẹ oṣelu gan an lo gbọdọ ṣe agbatẹru fun iru ẹni bẹẹ.
Koda, igbimọ adajọ kotẹmilọrun tun sọ pe o ti yẹ ki igbimọ oludajọ to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina ti dajọ wi pe Yusuf ko tiẹ koju oṣunwọn rara lati dije fun ipo gomina rara.
Adajọ Adumen koro oju si bawọn ẹgbẹ oṣelu ṣe maa n di ẹbi ijakulẹ wọn nile ẹjọ ru awọn adajọ.















