Wo kókó pàtàkì tó wà nínú ìkíni ọdún tí Ààrẹ Tinubu fi ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Nàìjíríà

Aworan ààrẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi ọrọ ikini ku ọdun Keresimesi ranṣẹ si awọn ọmọ orileede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ aarẹ sọ pe asiko ọdun Keresi mu anfaani wa faraalu lati jẹ adun ibaṣepọ ati irẹpọ laarin mọlẹbi to fi mọ idunnu pẹlu ifẹ ati irẹpọ to mu ki aye dun.

Ọrọ ikini akọkọ ree ti Tinubu yoo fi ransẹ si araalu lati igba to ti dori oye gẹgẹ bi aarẹ.

Lasiko ọdun yi, ọpọ lorileede Naijiria lo n kerora latari bi owongogo ati aisi owo ṣe gbode.

Ọdun keresimesi jẹ ọdun pataki fun awọn ọmọ lẹyin Kristi lagbaye ati ni Naijiria ni paapa.

Aarẹ ninu ọrọ rẹ mọ riri inira ti ọpọ, ni paapa, awọn to padanu ololufẹ n ba finra.

O sọ pe " asiko yi jẹ asiko lati gbaruku ti arawa tohun ti pọpọṣinṣin ọdun tori ọpọ ni yoo ma ṣe idaro awọn ti wọn padanu ati awọn mii naa ti wọn daro afojusun ti wọn ko ribi de ba"

Ọrọ ikini rẹ tun mẹnu ba awọn iyipada to n waye lorileede Naijiria ati bo pataki lati " mu agbega ati alaafia ba gbogbo awọn to farada inira to ba awọn iyipada yi wa"

Ninu awọn iyipada ti araalu mọ lara lasiko yi ni ipenija airi owo naa tori ọwọngogo nkan l'ọja ati bi owó Naira ti ṣe ṣoro lati ri l'awọn ipinlẹ kọọkan.

Laipẹ yi ni banki apapọ Naijiria tun jáde láti sọ pe awọn oniṣowo POS kan ati awọn ilé ifowopamọ lo n da wahala airi Naira na to gbode yi.

Tohun ti gbogbo atotonu awọn alaṣẹ ko jọ pe eyi ribi dẹkun inira t'araalu n koju tori owó to nira lati ri.

Ijọba kede ẹdinwo ida aadọta owo ọkọ irinajo

Ninu atẹjade aarẹ lasiko ọdun yi, o ni ijoba oun yoo tẹsiwaju ipese eto idẹkun fawọn ti o wa ninu ewu iṣẹ ati oṣi julọ ni Naijiria.

Lori eleyi a ri apẹrẹ pe bi ọjọ ọdun ṣe n sunmọ ni jọba kede idẹkun faraalu lori eto irinajo lasiko ọdun yi.

Ninu atejade ti ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ, Bayo Onanuga, fi sita loju opo Twitter o ni ijoba yoo san ida aadọta ninu ida ọgọrun owo ọkọ fawọn araalu to ba n rinrinajo l'awọn ọna kan.

Bẹẹ naa ni wọn kede pe wiwọ ọkọ reluwee ijọba apapọ yoo ba ọfẹ de lasiko ọdun yi.

Akọroyin BBC jade lati wo bi araalu ṣe n jẹ anfaani yi ti awọn kan sí sọ pe o mu idẹkun wa amọ eyi ko kaari gbogbo awọn to fẹ rinrinajo lasiko ọdun.

Afojusun ijọba ni pe ki ọmọ Naijiria mílíọ̀nù marun un jẹ anfaani ẹdinwo ati reluwee ọfẹ lasiko ọdun yi amọ bi eeyan ba foju wo iye awọn ti yoo rinrinajo lasiko ọdun eleyii ko le ran araalu.