Tinubu fi orúkọ àwọn 11 ṣọwọ́ sílé aṣòfin àgbà láti di adájọ́ nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Aarẹ Bola Tinubu lo ti ni ki ile aṣofin agba orilẹede Naijiria o fọwọ si iyansipo awọn mọkanla kan gẹgẹ bi adajọ nileẹjọ to ga julọ nilẹ yii.
Ojọru ọsẹ yii ni Aarẹ ile aṣofin agba, Godswill Akpabio, ka iwe ti Aarẹ fi ṣọwọ sile aṣofin naa.
Lọgan ni Akpabio dari iwe naa sọdọ igbimọ to n mojuto ẹka idajọ ati ọrọ ofin ti wọn si bẹrẹ ayẹwo awọn orukọ mọkanla naa gẹgẹ bi ajọ to n mojuto eto idajọ lorilẹede yii, NJC, fi ranṣẹ si Aarẹ Tinubu.
Ẹnikẹni to ba fẹẹ di adajọ nileẹjọ giga ilẹ yii ni NJC ni lati kọkọ fi orukọ rẹ ṣọwọ si Aarẹ, ti oun naa yoo si taari rẹ sile aṣofin agba fun ayẹwo ati ibuwọlu ki wọn to lee bura wọṣẹ fun iru ẹni bẹẹ.
Lara awọn mọkanla naa ni Adajọ Haruna Tsammani lati ila-oorun-ariwa ilẹ yii, to jẹ alaga igbimọ to gbọ ẹjọ ibo aarẹ lọdun yii.
Awọn to ku ni Moore Adumein lati guusu-guusu, Jummai Sankey lati aaringbungbun-ariwa, Chidiebere Uwa lati ila-oorun-guusu, Chioma Nwosu-Iheme lati ila-oorun-guusu, Obande Ogbuinya lati ila-oorun-guusu, Stephen Adah lati aaringbungbun-ariwa, Habeeb Abiru lati iwọ-oorun-guusu, Jamilu Tukur lati iwọ-oorun-ariwa, Abubakar Umar lati iwọ-oorun-ariwa ati Mohammed Idris lati aaringbungbun-ariwa.
Ileẹjọ to ga julọ naa lo ni mẹwaa pere ninu awọn adajọ mọkanlẹlogun to yẹ ko wa nibẹ.
Adajọ agba ilẹ yii, Olukayode Ariwoola, si ti ṣeleri pe oun yoo ri daju pe gbogbo awọn mọkanlelogun naa pe peerepe.
Ẹkun mẹrin pere ninu ẹkun idibo mẹfa to wa ni Naijiria lo ni aṣoju ninu awọn mẹwaa naa ti ẹkun meji ko si ni nkankan rara.
Ẹkun iwọ-oorun-guusu ati ila-oorun-ariwa lo ni adajọ mẹta-meta, ti ẹkun guusu-guusu ati iwọ-oorun-ariwa si ni meji-meji.
Ẹkun ila-oorun-guusu ati aaringbungbun-ariwa ni ko ni aṣoju kankan nibẹ rara.
Ti ile aṣofin agba ba fọwọ si awọn mọkanla naa, ẹkun ila-oorun-guusu ati aaringbungbun-ariwa ni yoo ni aṣoju mẹta-mẹta ninu awọn adajọ ọun.












