Ìjọba yóò yọ àádọ́ta mílíọ̀nù ọmọ Nàìjíríà kúrò nínú ìṣẹ́ àti òṣì - Mínísítà Edu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Ijọba apapọ ti ṣetan lati yọ aadọta miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu oṣi ati iṣẹ laarin ọdun mẹta ati aabọ.
Minisita ileeṣẹ ijọba to n ri si idojutoṣi ati ṣiṣe aanu ọmọnìyàn, Dokita Betta Edu lo fìdí ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwọrọ kan to ṣe lori ileeṣẹ tẹlifisan Channels.
"A n ṣiṣẹ lori eto lati yọ aadọta miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu oṣi ati iṣẹ laarin ọdun mẹta ati aabọ.
Amọ, kii ṣe iṣẹ ẹka ijọba ti mo jẹ adari rẹ nikan ni èyí.

Oríṣun àwòrán, Dr Betta Edu/Facebook
Oniriuuru ileeṣẹ ijọba ni yoo jọ ṣiṣẹ pọ lati rí pe eleyii di ṣiṣe.
Fún àpẹẹrẹ, ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sí okowo ati ileeṣẹ yoo kopa ribiribi ninu eto yii.
Ileeṣẹ ijọba yii lo n ṣagbatẹru awọn olokowo kekeeke.
Ẹwẹ, aarẹ Bola Tinubu ti ṣe agbekalẹ eyawo fáwọn olokowo kekeeke yii kaakiri orilẹ ede Naijiria," Dokita Edu ṣalaye.
Minisita naa ni ijọba mu eto lati mu ọgọọrọ ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ ati osi ni ọkunkundun.
Dokita Edu ni "Aarẹ Tinubu jẹ ẹnikan ti ko f'ọrọ awọn ti ko ri ọwọ họri ṣere rárá.
Gbogbo agbara ati ipa ti Tinubu ni lo n sa lati ri pe awọn ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ.
Oriṣiiriiṣi eto ni a ti ṣe agbekalẹ rẹ lati rí pe eyi wa si imuṣẹ.
Koda, a n ṣiṣẹ pọ pẹlu oniruuru ajọ kaakiri agbaye to fi mọ banki agbaye.
Ohun kan gboogi ti a fẹ ṣe naa ni lati mu aadọta miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ ati oṣi."














