Ìjọba àpapọ̀ kéde ìsinmi fún ayẹyẹ ọdún Keresimesi àti ọdún tuntun

Christmas 2023

Oríṣun àwòrán, getty images

Ijọba apapọ ti kede ọjọ karundinlọgbọn ati ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati ṣajọyọ ọdun Keresimesi.

Bẹẹ naa lo tun kede ọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024 gẹẹ bii isinmi lẹnu iṣẹ lati ṣajọyọ ọdun tuntun.

Ikede naa lo waye ninu atẹjade kan lati ọọfisi ileeṣe to n ri si ọrọ abẹle ni Naijiria.

Atẹjade naa ni, minisita fọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo le kede bẹẹ loruko ijọba apapọ, o tun ba awọn ọmọlẹyin Kristi ṣajọyọ ọdun Keresimesi.

O ni “Ọmọwe Tunji-Ojo rọ awọn Kristẹni ki wọn wo awokọṣe igbeaye Jesu Kristi.”

“Ki wọn maa wo awokọṣe awọn ẹkọ rẹ ni ti iwa irẹlẹ, iṣẹ ṣiṣẹ, aanu ati suuru, alaafia ati ododo ti ibi rẹ n ṣapẹrẹ.”

Minisita naa sọ pe ijọba apapọ ti ṣeto ebo to peye fun awọn araalu lasiko isinmi ọdun naa.

Nigeria

Oríṣun àwòrán, @MinOfInteriorNG

Ẹwẹ, Tunji-Ojo ke si awọn araalu lati mu eto abo ara wọn lọkunkundun, ki wọn si tọ awọn agbofinro lọ ti wọn ba kofiri iwa ọdaran kankan lagbagbe wọn.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, asiko pọpọṣinṣin ọdun jẹ akoko ti awọn eeyan gbọdọ maa ṣọra nitori awọn kọlọrọsi ti yoo fẹ lo anfani akoko naa lati ṣiṣẹ laabi.

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria ki wọn maṣe sọ ireti nu nitori ọdun 2024 yoo dara ju ọdun 2023 yii lọ.