Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Adejumo Lewis jáde láyé

Aworan Adejumo

Oríṣun àwòrán, Adejumo Lewis

Gbajugbaja oṣere tiata, Dejumo Lewis tí jade laye.

Agba oṣere naa lo ọgọrin ọdun ni oke eepẹ.

Saidi Balogun, gbajumo oṣere tiata lo kede ipapoda Lewis lori opo ayelujara rẹ lọjọ Satide.

O gbe fọnran oloogbe naa síta, to si, sọ pe "Od'igba, kí Ọlọrun tẹ ọ safẹrẹ rere, RIP"

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ohun to sokunfa iku Lewis ni ko ti han si araye bayii.

Ọpọ awọn oṣere tiata ni ọkùnrin ati obinrin lo bọ sori ayelujara lati saro eeyan wọn to lọ.

Lewis jẹ gbajumo oṣere tiata, o kopa ninu ere sinima 'The Village Headmaster lati ọdun 1968 si 1988, to jẹ pe oun lo kopa gẹgẹ Kabiyesi ninu sinima naa.

Awọn sinima mii to jẹ ti Lewis ni “A Place in the Stars” (2014), “Crossroads” (2020), and “Power of 1” (2018),