Àwọn oní POS àtàwọn báǹkì ló ń lẹ̀dí àpò pọ̀ kówó pamọ́ - CBN

Aworan owo naira

Oríṣun àwòrán, CBN/X

Banki àpapọ Naijiria, CBN ti kilọ fawọn to n lo POS at'awọn banki pe ki wọn ye lẹdi apo pọ kowo naira pamọ.

Adele ọga agba CBN, Sidi Ali lo sọ eyi di mimọ̀ ninu atejade kan to fi sita lalẹ Ọjọbọ.

Banki CBN sọ ninu atẹjade naa pe igbimọ pọ awọn atawọn to n fi POS ṣe okowo lo fa ọwọngogo na

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Banki CBN ni oun ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa, o si kilọ fawọn banki atawon to oni POS lati jáwọ, bi bẹẹ kọọ, wọn o dara wọn lẹbi.

CBN gbe atẹjade yii sita latari bi awọn araalu ṣe n pariwo ọwọngogo naira.

CBN wa rọ awọn araalu lati to awọn leti nipa ipenija tabi idojukọ ti wọn ba ni lori gbigba owo wọn.

O ti to bi oṣu meloo kan bayii t'awọn araalu ti n foju wina airowo gba yala ni banki tabi lọwọ awọn to n fi ẹrọ POS ṣe okowo.

CBN tun rọ awọn araalu lati maa lo ọna mii ti wọn mọ lati gba owo wọn.

Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ọwọngogo owo naira papaa jùlọ lasiko pọpọsinsin ọdun t'awọn eeyan nilo owo lati fi ra ounjẹ, aṣọ at'awọn nkan mii fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun.