Ọ̀gá Iléeṣẹ́ Crime Alert rí ẹ̀wọ̀n ọdún 75 he fún ẹ̀sùn jìbìtì

Aworan Olaniyan Gbenga Amos

Oríṣun àwòrán, X/EFCC

Oludasilẹ ileeṣẹ Crime Alert Security Network, ni Ibadan, Olaniyan Gbenga Amos ti dero ọgba ẹwọn lẹyin ti Ileẹjọ to n joko niluu Ibadan ni o jẹbi ẹsun jibiti.

Ẹwọn ọdun marindinlọgọrin ni Adajọ Bayo Taiwo ti ile ẹjọ giga to n joko niluu Ibadan, gbe kalẹ fun oludasilẹ ileeṣẹ Crime Alert Security Network, Olaniyan Gbenga Amos lori ẹsun jibiti naa.

Bẹẹ ba igbagbe Olaniyan ni ọwọ ajọ EFCC tẹ ni ọdun 2020 lẹyin to lu ọpọ eeyan ni jibiti owo idokowo pẹlu ileeṣẹ rẹ.

O se ileri pe oun yoo da owo ati ele ori owo pada fun awọn to ba dokowo sugbọn ọrọ gba ibo miiran jade, ti ko si ri owo naa san pada.

Ẹsun marindinlogogi ni EFCC ka si ẹsẹ Olaniyan niwaju ileẹjọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale gbe sita lọjọ Isẹgun, o ni Olaniyan ati ileeṣẹ rẹ, Detorrid Heritage Investment Limited ni wọn gbe lọ ileẹjọ ni ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2023.

Ọdun to kọja , ẹlẹrii ajọ EFCC, Juliet Odogu sọ fun ileẹjọ pe o to igba ni iye awọn eeyan ti Olaniyan lu ni jibiti ni owo to to aadọjọ milọnu naira.

O ni awọn eeyan san ẹgbẹrun marun un naira si milọnu mẹsan an naira fun Olaniyan lẹyin ti wọn ba dowopọ.

Bakan naa lo se afihan iwe akọsilẹ ti awọn eeyan naa fi san owo fun ileeṣẹ Olaniyan fun Ileẹjọ.

Gẹgẹ bii EFCC se sọ, Olaniyan ni wọn tun fẹsun pe o gba milọnu mẹdogun naira lọwọ Fadipe Ayorinde pẹlu ileri pe yoo gba ida ọgbọn pẹlu owo to fi dokowo lẹyin ọsẹ mẹfa.