Àwọn mẹ́sàn án móríbọ́ nínú ìjàmbá ọkọ̀ l’Ogun lọ́jọ́ àìsùn ọdún Kérésì

Oríṣun àwòrán, OGUNUPDATE/FACEBOOK
O kere tan, awọn eniyan mẹsan – ọkunrin mẹfa ati obinrin mẹta – ni ori ko yọ lọwọ iku nigba ti ọkọ meji lari mọra ni orita Orile-Imo, ni popona Abeokuta si Sagamu lọjọ Aiku, to jẹ ọjọ aisun ọdun Keresimesi.
Iroyin fi yeni pe awọn ọkọ mejeeji, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota kan ati bọọsi akero Mitsubishi kan lo kọ lu ara wọn, leyi to mu ki ọkọ bọọsi naa o takiti to si fẹyin le’lẹ, ti ọkọ toyota si mori le igbo.
Oṣojumikoro kan ṣalaye fawọn akọroyin pe ere asaju lo ṣokunfa ijamba ọkọ ọhun.
O wi pe “ohun ti mo ri ni pe awọn ọkọ mejeeji n sare bọ ni, ti ọkan ninu wọn si padanu idari ọkọ rẹ, leyi to muu kọlu ikeji”.
Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ aabo oju popo (FRSC) nipinlẹ Ogun, Florence Okpe, to fidi iṣẹlẹ mulẹ wi pe ere asapajude awọn awakọ mejeeji lo faa ti wọn fi kọlu ara wọn.
Ekpo wi pe “ni tootọ ni awọn ọkọ meji kọlu ara wọn nitosi Orile-Imo ni opopona Sbeokuta si Sagamu, amọ ko si ẹmi kọkan to ba iṣẹlṣ naa lọ bo ti lẹ jẹ pe awọn mẹsan lo wa ninu awọn ọkọ naa.
“Ọkunrin mẹfa ati obinrin mẹta lo wa ninu awọn ọkọ naa, ti awọn obinrin mẹtẹẹta si farapa, ti wọn si ti n gba itọju nileewosan Idera nilu Sagamu.
“Ojoojumọ la maa n lọgun rẹ pe ki awọn awakọ o ma maa sare asaju loju popo, paapaa ju lọ lakoko ọdun yii, nitori bi awọn ọkọ yoo ṣe pọ loju ọna, amọ wọn kii tẹle amọran wa.
“O ṣe pataki fawọn awakọ lati maa tẹle awọn irinna ti a ti la kalẹ lati lee pinwọ ere asapajude ki irufẹ iṣelẹ yii o ma baa waye.”












