Pásítọ̀ tí ọmọ ìjọ rẹ̀ tó lé ní 400 kú lẹ́yìn tó ní kí wọ́n gb'àwẹ̀ foju balé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, getty images
Ijọba orilẹ-ede Kenya ti fẹsun igbesumọmi kan pasitọ ijọ The Good News International Ministries (GNIM), Paul Mackenzie, lẹyin ti awọn ọmọ ijọ rẹ to le ni irinwo ku latari aṣẹ to pa fun wọn.
Inu oṣu Kẹrin, ọdun 2023 ni wọn fi ṣikun ofin mu Mackenzie, lẹyin ti wọn ṣawari ọpọ oku ọpọ eeyan, ti iroyin si sọ pe ebi lo pa lara awọn eeyan naa ku.
Awọn agbofinro ni Kenya ni ọkunrin naa atawọn afurasi mẹ́rìnléláàdọ́rùn ún mii yoo foju bale ẹjọ lọjọru.
Bi Mackenzie ṣe wọ gau
Ọkunrin naa, to pe ara rẹ ni pasitọ ti sọ pe ohun ko jẹbi ẹsun iku awọn eeyan naa ti wọn fi kan oun.
Apapọ oku eeyan 429 ni awọn alaṣẹ wu jade nibi ti wọn sin wọn si lagbegbe Shakaola, ti ọmọde si wa lara wọn.
A gbọ pe ṣe ni Mackenzie sọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ, Good News International Church, pe ki wọn lọ sibi ti wọn ku si naa lati maa reti opin aye to fẹ de.

Oríṣun àwòrán, getty images
Nigba ti wọn de ibẹ, ọpọ wọn lo gba awẹ titi doju iku lọna ati wọn iọba ọrun, ti a si gbọ pe ijọ naa lo sin lara oku awọn eeyan ọhun.
Ọkan lara awọn oṣojumi koro sọ fun BBC pe ijọ naa sọ fun awọn pe ki wọn bẹrẹ si n gbawẹ lati oṣu Kinni ọdun to kọja ki awọn le ri ọrun wọ.
Amọ Mackensie ti fesi pe ijọba ko le so oku awọn eeyan mọ oun lọrun nitori lati ọdun 2019 ni oun ti gbe ijọ naa ti pa.
Ṣaaju ni awọn agbofinro ti kọkọ bẹ ile ẹjọ pe ko fun awọn laaye lati tẹsiwaju lati fi Mackenzie si atimọle titi ti awọn yoo fi pari iwadii wọn.
Wayi o, wọn ni awọn ti ni ọpọ ẹri lati gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ bayii.
Yatọ si ẹjọ oku awọn ọmọ ijọ ti Mackenzie n jẹ, oun atawọn afurasi to ku tun n jẹjọ lori ẹsun fifi iya jẹ ọmọde lọna aitọ.














