Èèyàn mẹ́jọ kú, ọ̀pọ̀ di àwátì nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi ní Niger

Oríṣun àwòrán, others
Ko din ni eeyan mẹjọ to ti ku ti ọpọlọpọ miran si tun ti di awati bayii ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ ojuomi kan to ri si agbami ni ipinlẹ Niger lẹkun iwọ oorun ariwa NAijiria.
Iroyin sọ pe ọgọrun eeyan lo wa ninu ọkọ oju omi naa nigba ti iṣẹlẹ ijamba naa waye.
Ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn olugbe ileto Dugga kan n lọ si ọja ni ipinlẹ Kebbi lati ta ere ati ereke.
- Ọkọ̀ ojú omi tó kó ọgọ́rùn ún èèyàn rì ní ìpínlẹ̀ Niger, mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n jade láyé
- Èèyàn 20 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dojúdé lójú agbami ní Kebbi
- "Ọkùnrin kan pàdánù ìyàwó rẹ̀ méjì àti ọmọ márùn ún sínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi Kwara"
- Èèyàn mẹ́ta jóná, ọ̀pọ̀ farapa níbí ìjàmbá tírélà mẹ́ta tó gbiná ní Ilorin
'Atẹgun to gbodi lo fa ijamba ọkọriri naa'

Oríṣun àwòrán, bbc/Ahmed ambali
Iṣẹlẹ ijamba ọkọ ojuomi ti n di lemọlemọ lagbami orilẹede Naijiria, paapaajulọ lagbegbe naa.
Ohun ti awọn alaṣẹ maa n so rọ mọ awọn iṣẹlẹ wọnyii gẹgẹbi okunfa wọn naa ni aisi amojuto to yẹ fun awọn ọkọ ojuomi wọnyii ati akoju ero.
Alukoro fun ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ̀ Niger, Ibrahim Hussaini ṣalaye pe ayipada to de ba ọwọja atẹgun lojiji lo doju ọkọ ojuomi to ti kun akunya naa de omi.
Oku eeyan mẹjọ ni wọn ti ri, eeyan marun un ni wọn si ti doola ẹmi wọn.
Amọṣa, gẹgẹbi Hussaini ṣe sọ, wọn ṣi n wa gbogbo awọn yoku.















