Ọkọ̀ ojú omi tó kó ọgọ́rùn ún èèyàn rì ní ìpínlẹ̀ Niger, mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan mẹrindinlọgbọn lo ti jade laye nipinlẹ Niger lẹyin ti ọkọ oju omi kan ri nibẹ.
Ọjọ Aiku ni ọkọ oju omi ọhun, ti wọn fi pako ṣe ri.
Nnkan bii ọgbọn eeyan ni wọn ti doola ẹmi wọn nibẹ.
Lara awọn ọgọrun eeyan ti ọkọ oju omi naa ko ni awọn obinrin atawọn ọmọ wẹwẹ wa, ti awọn eeyan naa si n gbe lawọn abule to wa laarin Jebba ati adagun omi Kainji, ni Mokwa.
Agbẹnusọ gomina ipinlẹ Niger, Bologi Ibrahim, sọ pe apapọ awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ori omi, awọn oluwẹ laarin ilu, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, NEMA, lo yọju sibẹ lẹyin iṣẹlẹ naa lati doola awọn eeyan.
Ko si ẹni to tii le sọ ohun pato to ṣokunfa iṣelẹ naa.
Amọ ọgbẹni Ibrahim da ẹbi iṣẹlẹ ru bi ero ṣe pọ ju bo ẹ yẹ ninu ọkọ ọhun, ati bi awọn ero ọkọ naa ko ṣe ni aṣọ to n lefoo lori omi ‘life jacket.’
Awọn alaṣẹ sọ pe pupọ ninu awọn ti ọrọ naa kan lo n rekọja lori omi naa lo sinu oko wọn.
Ninu oṣu Kẹfa ọdun yii irufẹ iṣẹlẹ kan yii naa waye, nibi ti ọgọrun eeyan ti padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n lọ si ipinlẹ Niger.












