Ọkùnrin kan gé orí ọmọge tí wọ́n jọ lọ sí hòtẹ́ẹ̀lì

Aworan akọle ile itura kan

Oríṣun àwòrán, others

Iwadii to nipọn ti bẹrẹ bayii lati ṣawari ọkunrin kan to ge ori ọrẹbinrin rẹ to gbe lọ si ile itura nipinlẹ Adamawa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọjọru, lọkunrin tawọn ọlọpaa ṣi n wa naa wọle si ile itura ọhun pẹlu ọmọge kan.

A gbọ pe nigba to ṣe diẹ lọkunrin naa jade pada loun nikan to si sọ fun oṣiṣẹ to n da awọn alejo lohun pe oun fẹ lọ ra nnkan, oun n bọ .

Oṣiṣẹ ile itura ọhun to wa nijọba ibilẹ Ariwa Yola, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa fi orukọ bo laṣiri, sọ pe nigba ti ọkunrin naa ko pada fun igba pipẹ ni wọn lọ wo yara to gba.

O ni nibẹ ni wọn ti ri ọmọge to gbe wa ninu agbara ẹjẹ, ti ko si ori lọrun rẹ mọ.

aworan maapu Adamawa

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, Afọlabi Babalọla to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣalaye pe iṣẹ ti n lọ labẹnu lati wadii ohun to ṣẹlẹ ati ọkunrin to gbe ọmọge naa wa sileetura.

Kọmiṣọna ọlọpaa Afọlabi rọ awọn olotẹẹli, pe ki wọn maa foju ṣọri nipa awọn alejo ti wọn n gba.

O lẹni ti wọn ba ri i pe iṣẹsi rẹ n mu ifura dani, ki wọn tete gbe igbesẹ ifisun lori rẹ.

Bakan naa lo rọ awọn eeyan ipinlẹ Adamawa lati fọkanbalẹ.

Afọlabi sọ pe gbogbo ẹka eto aabo ipinlẹ naa lo n ṣiṣẹ pọ bayii lati mu ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iwa ipaniyan yii, ijọba yoo si fi wọn jofin bo ṣe yẹ.