Kí ló mú Jaiye Kuti gbìyànjú láti fi ìgbéyàwò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta?

Aworan Jaiye Kuti

Oríṣun àwòrán, Instagram/jayeola_monje

Gbajugbaja oṣere tiata, Jaiye Kuti ni o to ida marundinlaadọrun obinrin to fẹ ẹ kuro ninu igbeyawo wọn.

Arabinrin Kuti ni oun gan-an ti gbinyanju lati kuro ninu igbeyawo oun ni igba mẹta ọtọọtọ sugbọn sibẹsibẹ oun si bara oun ninu igbeyawo naa.

O sọrọ yii lasiko to n ba Gistzlife sọrọ, o wa jẹ ko di mimọ pe awọn tọkọtaya ma n mọ ara wọn daada ninu igbeyawo ju ti igba ti wọn jọ jade papọ lọ.

Kuti fikun pe gbogbo ọkunrin lo ni ero lati yan iyawo wọn jẹ eyi to ma n mu ki obinrin ni ero lati kuro ni ile ọkọ.

“Ti o ba bi awọn obinrin, ida marundinlaadọrun ninu wọn fẹ kuro ninu igbeyawo wọn.

“Emi gan gbinyanju lati kuro ninu igbeyawo mi ni igba mẹta."

O ni, ti ọkunrin ba fẹ fẹ obinrin, wọn yoo t'ọju obinrin naa, sugbọn ti wọn ba fẹ wọn tan, ti ọmọ ba tun wọ inu igbeyawo bẹẹ, nnkan yoo yi pada.

“Ọkunrin ko ṣe da a duro ti wọn ba fẹ yan iyawo wọn jẹ.”