Àwọn oníṣẹ̀ṣe péjú pẹsẹ̀ síbi ayẹyẹ ọdún Iyemọja nílùú Babanloma ní Kwara

Aworan Arugba

Ilu Babanlmo ni ijoba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara gbalejo ọgọọrọ awọn oniṣẹse ni Ọjọbọ oṣu Kinni lati se ayẹyẹ ọdun Iyemọnja ni ilu naa.

T'ilu ti'fọn ti liili fi wọ ọja ni wọn fi ki arugba Iyemoja kaabọ laarọ Ọjọbọ sibi ajọdun naa.

Nkan bi ago mẹwa owurọ ni arugba Iyemọja wọlu lẹyin ti o ti lọ si odo ni owurọ pẹlu awọn oniṣẹṣe ti wọn ti lọ ṣe adura.

Lasiko to n ba aṣoju BBC Yoruba sọrọ, ọba iṣẹṣe ipinle Kwara, Ajakori Ibrahim Oloye Balogun olu ọdẹ ilu Baba lomọn ṣalaye pe ọdọọdun ni ọdun Iyemoja maa n waye ni ilu na.

O ṣalaye siwaju si pe ọdun Iyemoja bẹrẹ ni ilu naa nigba iwasẹ lasiko ti awọn agboole Ègún ọkọ wa tẹdo si ilu naa ti wọn si gbe oriṣa Iyemoja wọn dani.

Lati gba naa ni wọn ti n ṣe ayẹyẹ ọdun ọhun ni ilu Babalọmon, gbogbo awọn oniṣẹṣe ilu naa lo si jọ maa n ṣe ọdun naa titi di asiko yi.

Aworan Arugba
Ọdun Iyemoja

Alaye lori idi t wọn fi n ṣe ọdun Iyemọja ni ilu Babanlomo

Wọn n ṣe ọdun Iyemọja ni ilu Babanloma nitori pe wọn ni gbagbọ ninu rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn oriṣa ti wọn n ran si Eledumare nigba iwasẹ tí wọn si n ṣee titi di asiko yi.

Ti arugba Iyemọja ba ti de lati odo yoo bẹrẹ si ni wọn omi si inu ilu pẹlu iwure si ilu, ti wọn yoo si maa kọrin fun un, tawon onilu naa yio si maa sọ kọngọ silu.