Ọkọ gún ìyàwó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ pa, ó tún dáná sun ilé mọ́ ọ lórí l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin kan, ẹni ọgbọn ọdun, Motunrayo Olaniyi ni o ti dero ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin to gun iyawo rẹ to sẹṣẹ fẹ sile, Olajumoke lọbẹ pa ni agbegbe Amazing Grace Estate, Elepe niluu Ikorodu nipinlẹ Eko.
Iṣẹlẹ naa lo waye ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, lẹyin ti ede aiyede bẹ silẹ laarin tọkọtaya naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ wọn, Benjamin Hundeyin fi lede fun awọn akọ̀ròyìn, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe Motunrayo gun iyawo rẹ lọbẹ ni ọpọ igba, to si tun ti mọ inu ile wọn ko to di pe o dana sun ile naa.
Hundeyin fikun pe afurasi naa fi apa si ara ti ẹ naa lẹyin to sekupa iyawo rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn de sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti wọn si ri oku Olajumoke ninu ile naa lẹyin ti wọn pa ina to n jo.
“A gba ipe ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa ni agọ wa ni Ikorodu pe, tọkọtaya tuntun kan, ti orukọ wọn n jẹ Motunrayo Olaniyi, ẹni ọgbọn ọdun ati iyawo rẹ, Olajumoke, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ni ede aiyede bẹ silẹ laaarin wọn ni ile wọn ni Amazing Estate , Elepe niluu Ikorodu.
“Lasiko yii ni ọkọ gun iyawo rẹ lọbẹ pa, to si ti mọ ile, ko to dana sun ile naa.”
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gbe Olaniyi lọ si ile iwosan nibi to ti gba itọju ko to di pe wọn mu lọ si ahamọ.
Bakan naa ni wọn ti gbe oku oloogbe lọ si ile igbe oku si ni Ikorodu fun ayẹwo, autopsy.
Hundeyin ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.















