Mọ̀ nípa Comfort àti Tina tó ń ṣe ọṣẹ fáwọn ilé ẹ̀kọ́

Àkọlé fídíò, Mọ̀ nípa Comfort àti Tina tó ń ṣe ọṣẹ fáwọn ilé ẹ̀kọ́
Mọ̀ nípa Comfort àti Tina tó ń ṣe ọṣẹ fáwọn ilé ẹ̀kọ́

Akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun meji ni Comfort Fiadzigbe ati Tina Alorleve, ti awọn mejeeji jẹ oludasilẹ ileeṣẹ ọṣẹ Fresh and Lovely n pese ọṣẹ fun ni awọn ile ẹkọ kan lorilẹede Ghana.

Ọmọ orilẹede Ghana ni awọn obinrin mejeeji yii, to si jẹ pe ajọ ẹlẹyinju aanu Dream Big Ghana to n ṣeto imọtoto ati kikọ awọn ile igbọnsẹ lo kọ Comfort ati Tina niṣẹ.

Ọṣẹ naa ni wọn ni okun fun eroja aṣaraloore potassium, ti wọn si ni adi dudu pẹlu.

Comfort Fiadzigbe ni gẹgẹ bi iya ọlọmọ mẹta, oun pinnu lati ṣe ọṣẹ nitori awọn ọmọ rẹ maa n ṣere pupọ ni ilẹ, ti o si maa n fa ọpọlọpọ asian.

O ni eyi maa n jẹ ki wọn se aarẹ ni gbogbo igba.

“Lati le ran ọpọ lọwọ ati lati fi pawo ni a fi da Fresh and Lovely silẹ.

“Bakan naa ni a n se idanilẹkọọ nipa ọwọ fifọ nile ẹkọ.”

Aworan Comfort ati Tina