Ìjọba ìbílẹ̀ 22 já mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APP lọ́wọ́ nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní Rivers

Aworan ẹgbẹ oṣelu APP

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹgbẹ oṣelu Action Peoples Party ti jawe olubori nibi eto idibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Rivers nibi ti ẹgbẹ naa ti bori nijọba ibilẹ mejilelogun ninu mẹtalelogun to wa ni ipinlẹ naa.

Ọga agba fun ileeṣẹ to n risi eto idibo nipinlẹ Rivers, RSIEC, Adajọ Adolphus Enebeli lo kede esi idibo naa lọjọ Satide, ọjọ karun oṣu kẹwaa, ọdun 2024 niluu Port Harcourt.

Igba akọkọ ree ti ẹgbẹ oṣelu alatako yoo bori eto idibo ijọba ibilẹ lati ọdun 1999.

Ọpọ igba ni o jẹ pe ẹgbẹ oṣelu to wa ni ijọba lo ma n bori eto idibo ijọba ibilẹ.

Enebili ni esi idibo ijọba ibilẹ Etche ni wọn ko ti kede nitori wọn si n ka ibi naa lọwọ.

O wa fi da awọn eeyan ipinlẹ Rivers loju pe ajọ RSIEC yoo kede esi idibo kede ti wọn ba ti ka ibo naa tan.

Bakan naa lo sapejuwe eto idibo naa gẹgẹ bii eyi to waye ni ilana alaafia, ti ko si rogbodiyan.

Enebeli kede Vincent Reuben Obu – Abua/Odual, Chibudom Ezu – Ahoada-East, Arakunrin Iyekor Ikporo – Ahoada-West, Arabinrin Tonye Oniyide – Akuku-Toru, Lazarus Gogote Nteogwuile – Andoni gẹgẹ bii awọn to bori eto idibo naa.

Bakan naa lo da orukọ Dr Sule Amachree – Asari-Toru, Dame Anengi Barasua – Bonny, Dr Harry Agiriye – Degema, Oloye Brain Gokpa – Eleme, ati David Omereji – Emohua.

Monday Dumiye – Gokana, Israel Abosi – Ikwerre, Martins Nwigbo – Khana, Chijioke Ihunwo – Obio/Akpor, Prince Isaac Umejuru – Ogba-Egbema-Ndoni, Ishmael Oforibika – Ogu/Bolo, Dr Igwe Achese – Okrika, Promise Reginald – Omuma, naa bori eto idibo ni ijọba kowa wọn.

Awọn yooku ni Enyiada Cookey-Gam – Opobo/Nkoro, Gift Okere – Oyigbo, Ezebunwo Ichemati – Port Harcourt, ati Matthew Nenubari Dike – Tai.

Kí ló ń fa awuyewuye lórí ètò ìdìbò nìjọba ìbílẹ̀ tó ń wáyé ní Rivers lónìí

Àpòtí ìbò àtàwọ òṣìṣẹ́ elétò ìbò
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Rivers, RSIEC ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìdìbò láti yan àwọn alága àti káhúnsílọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.

Ní àwọn wọ́ọ̀dù 319 àti ìbudó ìdìbò 6,366 ni ètò ìdìbò náà yóò ti wáyé.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ṣe sọ, èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ló forúkọ sílẹ̀ láti dìbò níbi ètò ìdìbò gbogbogboò tó wáyé ní Nàìjíríà lọ́dún 2023 – àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn èèyàn yìí ni RSIEC ń ṣàmúlò níbi ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ yìí.

Ẹgbẹ́ òṣèlú méjìdínlógún nínú mọ́kàndínlógún tó wà ní Nàìjíríà ló ń kópa nínú ètò ìdìbò ọ̀hún. Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party tó jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ ní Rivers nìkan ni kò kópa nínú ètò ìdìbò náà.

Ṣáájú àkókò yìí, ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ ló máa ń jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà àmọ́ ó ti fojú hàn báyìí pé ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ló máa wà ní ipò náà fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún 1999 tí ètò ìṣèjọba àwaarawa ti bẹ̀rẹ̀ padà ní Nàìjíríà.

Gómìnà Siminialayi Fubara wòye pé òun ni òun pàdánù jùlọ níbi ètò ìdìbò náà nítorí ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀, PDP ni kò kópa nínú ètò dìbò náà.

Ó ní òun ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà tó dájọ́ pé ètò ìdìbò náà gbọdọ̀ wáyé, pé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbọdọ̀ ní alága tí wọ́n dìbò yàn àti pé gẹ́gẹ́ bí gómìnà, òun gbọdọ̀ tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́.

Kí ló dé tí ètò ìdìbò yìí ṣe pàtàkì?

Gómìnà Fubara ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, RSGH

Ètò ìdìbò yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà pàṣẹ pé àwọn alága tí ìlú dìbò yàn ni wọ́n gbọdọ̀ máa wà nípò ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ káàkiri Nàìjíríà.

Ìpínlẹ̀ mẹ́wàá ló ti ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lẹ́yìn tí Supreme Court gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀, táwọn ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Jigawa àti Benue náà sì ń ṣe ti wọn lónìí.

Nínú oṣù Kẹwàá yìí kan náà ni Plateau, Kaduna, Kano àti Cross River náà yóò ṣe ti wọn.

Gómìnà Fubara nínú ọ̀rọ̀ tó sọ lọ́jọ́rú nígbà tó ń bá àwọn aráàlú sọ̀rọ̀ ní ìdásí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ló jẹ́ kí ilé ẹjọ́ fún àwọn ní oṣù mẹ́ta láti ṣe àmúṣẹ àṣẹ náà àti pé ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹwàá ni wan fún àwọn dà láti ṣètò ìdìbò náà.

Ó ní ìdí nìyí tí òun fi fún àjọ tó ń ṣètò ìdìbò lábẹ́nú ní ìpínlẹ̀ náà láṣẹ láti ṣètò ìdìbò àti pé òun máa tàpá sòfin ilé ẹjọ́ tí òun kò bá jẹ́ kí wọ́n ṣètò ìdìbò náà.

Kí ló dé tí PDP kò fi kópa nínú ètò ìdìbò náà?

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP àtàwọn apá kan lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ní ìpínlẹ̀ Rivers ti dúnkokò pé àwọn kò ní gbà kí ètò ìdìbò náà wáyé.

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Rivers, Aaron Chukwuemeka lásìkò tí wọ́n ṣe ìwọ́de lọ sí ọ́fíìsì iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti DSS lọ́jọ́bọ̀ tó kọjá ní àwọn kò ní lè fọwọ́ lẹ́rán kí RSIEC máa ṣètò ìdìbò lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Wọ́n ní àwọn ṣe ìwọ́de náà láti rán àwọn iléeṣẹ́ náà létí pé ilé ẹjọ́ kan ti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé RSIEC kò gọdọ̀ ṣètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ àti pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà kò gbọdọ̀ kópa.

Chukwuemeka ní nítorí ẹgbẹ́ tó máa ń bọ̀wọ̀ fún òfin tí àwọn jẹ́ ni àwọn ṣe kàn sí àwọn iléeṣẹ́ náà láti rán wọn létí lórí ohun tí ilé ẹjọ́ wí àti pé àwọn kò ní máa wò kí wọ́n máa ṣètò ìdìbò láì sí ẹgbẹ́ àwọn níbẹ̀.

Onírúurú ìdájọ́ ilé ẹjọ́

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe ìwọ́de lọ sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti DSS

Oríṣun àwòrán, BARIKUI FELIX

Láti ìgbà ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Siminialayi Fubara àti ẹni tó gba ipò fún, Nyesom Wike ni oríṣiríṣi èèyàn tó jẹ́ alátìlẹyìn fáwọn méjéèjì ti ń pe ẹjọ́ oríṣiríṣi láwọn ilé ẹjọ́ káàkiri Nàìjíríà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹjọ́ náà ló wà ní ilé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ ìlú Abuja àti ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Rivers, Port Harcourt. Bákan náà ni àwọn míì wà ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn, kódà ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ kan ni.

Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú oríṣiríṣi ti ló sílé ẹjọ́ lórí ètò ìdìbò tó ń wáyé yìí.

Ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024 ni Adájọ́ I.P.C. Igwe ti ilé ẹjọ́ gíga Rivers pàṣẹ pé kí RSIEC tẹ̀síwájú lórí ètò ìdìbò náà àti pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin Nàìjíríà.

Àmọ́ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá ni ilé ẹjọ́ mìíràn tún gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé ètò ìdìbò náà kò gbọdọ̀ wáyé látàrí ẹjọ́ tí àwọn ikọ̀ kan lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC pè tako RSIEC.

Adájọ́ Peter Lifu ti ilé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ Abuja ní RSIEC kùnà láti tẹ̀lé àwọn ìlànà tó de ètò ìdìbò pé wọ́n gbọdọ̀ fi àtẹ bí ètò ìdìbgò náà léde ní ó kéré tí ètò ìdìbò náà bá ku oṣù mẹ́ta.

Adájọ́ Lifu tún pàṣẹ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò gbọdọ̀ pèsè ààbò níbi ètò ìdìbò ọ̀hún.

Nígbà tí wọ́n ń fèsì sí ìròyìn pé INEC ló fún RSIEC ní orúkọ àwọn olùdìbò ní Rivers, ọ̀gá àgbà INEC ní Rivers, Johnson Alalibo ní àwọn kọ́ ló pèsè orúkọ náà fún RSIEC.

Alalibo tó ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni RSIEC kàn sí àwọn láti pèsè orúkọ náà àmọ́ àwọn kò ì tíì parí ìgbésẹ̀ tí ilé ẹjọ́ fi pàṣẹ pé àwọn kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ àti pé ìdí nìyẹn tí àwọn kò fi gbe kalẹ̀ fún wọn.

Ṣùgbọ́n ọ̀gá àgbà RSIEC, Adolphus Enebeli ní àwọn yóò tẹ̀síwájú lórí ètò ìdìbò táwọn fẹ́ ṣe ní ìbámu pẹ̀lú òfn RSIEC.