'Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ló n dá ètò ìsìnkú bàbá wa, Taiwo Akinkunmi dúró'

Aworan Pa Taiwo Akinkumi ati aṣia Naijiria

Oríṣun àwòrán, @ABDULLARHI/bbc/olubayode alebiosu

Awọn ẹbi baba agba, Oloogbe Taiwo Akinkunmi, ẹni to fun asia orilẹ-ede Naijiria ni awọ ewe ati funfun, ti ṣalaye idi ti wọn ko ṣe ti i sin baba naa lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2023 to ti papoda.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, igbimọ ti ijọba gbe kalẹ lati sinku Alagba Akinkunmi ni ko ṣe ojuṣe wọn.

Ẹbi Akinkunmi sọ pe igbimọ naa lo n fi eto isinku baba to gba oye OFR naa falẹ, ti wọn ko jẹ kawọn ṣẹyẹ ikẹyin to yẹ fun un.

Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe, Ọgbẹni Akinkunmi Samuel, sọ pe ti ijọba ko ba ṣetan lati fun baba awọn ni ẹyẹ ikẹyin bi wọn ṣe ṣeleri, ki wọn fun ẹbi rẹ laaye lati ṣe iwọn ti awọn le ṣe.

Gẹgẹ bawọn ẹbi ṣe wi, wọn ni ẹbi Akinkunmi ti fẹẹ ṣayẹyẹ isinku naa funra wọn lọjọ keje ati ikẹjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023, ṣugbọn ijọba ipinlẹ Ọyọ fagile e nitori ko si aṣoju ijọba kankan nibẹ lasiko ti awọn mu ọjọ meji ọhun.

Wọn ni awọn ko fẹẹ ba ijọba fa nnkan kan lori isinku, awọn ko si fẹẹ ko da bii pe awọn ni nnkan kan tawọn fẹẹ jẹ ninu rẹ.

Eyi lo fa a tawọn fi gbe ohun to n ṣẹlẹ nipa isinku naa sita fun aye lati gbọ, ki gbogbo eeyan le mọ ohun to n ṣẹlẹ gan-an.

Ta a ni Oloogbe Taiwo Akinkunmi

Alagba Taiwo Akinkunmi lo ṣe agbekalẹ awọ ewe ati funfun ti asia Naijiria ni.

Eyi waye lasiko ti Naijiria n mura lati gba ominira lọwọ Britain ni 1960.

Lọdun 2014, Aarẹ Goodluck Jonathan to wa nipo nigba naa, fi ami-ẹyẹ Order Of The Federal Republic (OFR) da Alagba Akinkunmi lọla.

Aworan aṣia Naijiria

Oríṣun àwòrán, BBC/Olubayode alebiosu

Oloogbe Akinkumi lọ si ile ẹkọ alakọọbẹrẹ Baptist Day n’Ibadan, o si tun lọ si Ibadan Grammar School.

Oloogbe Taiwo Akinkunmi rin irin ajo lọ si London lati kẹkọọ nipa ọgbin, nibẹ lo si ti gbọ ipolongo pe ijọba n wa ẹni to le ṣe asia Naijiria ti yoo jọju.

Akinkunmi ṣe asia tiẹ, o fun un lawọ ewe ati funfun, o si fi ranṣẹ.

Tiẹ ni wọn gba wọle ninu bii igba (200) tawọn eeyan mi-in naa fi ranṣẹ lasiko kan naa.

Ẹni ọdun mẹtalelogun (23) ni Taiwo nigba naa, wọn si san ọgọrun-un pọn-un ( £100) fun un gẹgẹ bi owo iṣẹ rẹ.

Lẹyin ilu oyinbo, Akinkunmi pada si Naijiria, o si darapọ mọ ileeṣẹ eto ọgbin, nibi to ti ṣiṣe karakara.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun (87) ni ko too jade laye.