Báyìí ni wọ́n ṣe ṣayẹyẹ ìrántí ọmọ Oyo tó tẹ ìlú Isakete ní orílẹ̀ èdè Benin dó, tó sì di Alfa ńlá níbẹ̀

Ilu Isakete lorilẹede Benin Republic gba alejo oriṣiiriṣii eeyan lopin ọsẹ to kọja nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade ninu keu to waye nibẹ.
Gẹgẹ bi itan ṣe fidi rẹ mulẹ, lati ilu Oyo ni Ọba Maro ti lọ tẹdo si ilu Ifayin titi wọ ilu Isakete ni orilẹ ede Olomonira Benin.
Iṣẹ Ọdẹ ni Ọba Maro yan laayo, to si tun jẹ ẹni to maa n da ifa.
Ọba Maro bi awọn ọmọ ti ọkan ninu awọn ọmọ rẹ si n jẹ Olufade.
Olufade bẹrẹ si ni tọ ipasẹ baba rẹ nipa iṣẹ ọdẹ ti wọn yan laayo, to si tun maa n difa pẹlu amọ nigba to ya lo yipada di musulumi.
Ọmọ ọkunrin kan ṣoṣo ni Olufade bi iyẹn Karimu Lasisi to si fi ọmọ naa si ile Kewu lati lọ kọ nipa imọ ẹsin Islam.
Karimu kẹkọọ kewu yege to si wa lara awọn to kọkọ ṣe walima Kurani ni ilu Isakete nigba naa, to si tara bẹẹ di Alfa nla to n ṣe waasi kaakiri ni ilu Isakete nigba naa.
Gẹgẹ bi itan ṣe fi mulẹ, ọpọlọpọ eniyan ni ilu Isateke lo tara Karimu Lasisi gba ẹsin Islam nigba naa latara mọṣalaṣi ati ile kewu kekere to kọ siluu naa nigba naa.
Ni ọjọ Kẹindinlọgbọn oṣu Kiini ọdun 1984 ni Karimu Lasisi Dagbere faye ti wọn si sin oku rẹ ni ọjọ Keji tii ṣe ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kiini ọdun 1984 tii ṣe ogoji ọdun si asiko yii.
Ni iranti oloogbe Karimu Lasisi ni awọn ẹbi ati ara ilu Isakete fimọ ṣọkan lati ṣe atunkọ mọṣalaṣi ati ile kewu to n lo ko to jade laye pẹlu ṣiṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade fawọn ọmọ ile kewu to n kẹkọọ nile ẹkọ naa.
Minisita fun eto ẹkọ alakọọbẹrẹ ni orilẹ ede Benin, Salimane Akirimou ti oun naa bawọn peju sibi ayẹyẹ naa rọ awọn eniyan lati jina si iwa ẹlẹyamẹya ati ija ẹsin.
Bakan naa ni obinrin to kọkọ gboye Ọmọwe ninu ẹkọ kewu, Arabinrin Widad Naibi naa wa lara awọn to ṣayẹyẹ nibi eto naa.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn tun ṣe Waliman fun bakan naa.
Wọnyii ni awọn aworan bi nkan ṣe lọ nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade naa niluu Isakete lorilẹede Benin Republic.





























