Àlùbamí ni ọkọ mi tẹ́lẹ̀ máa ń lù mí tí Man United bá ti fìdírẹmi - Ìlúmọ̀ọ́ká òṣèbínrìnrin

Oríṣun àwòrán, Victoria Inyama/Instagram
Gbajugbaja oṣerebinrin, Victoria Inyama ti sọ pe niṣe ni ọkọ oun maa n lu oun lalubami nigba kugba ti ẹgbẹ agbabọọlu to fẹran, Manchester United ba ti fidirẹmi ninu ere bọọlu.
Ninu ifọrọwwerọ ti oi ṣe pẹlu Chude Jideonwo, Inyama sọ pe bi ọkọ oun ṣe maa n lo oun ni aluki lo jẹ ki oun korira ẹgbẹ agbabọọlu Man United bayii.
O ni nigba kugba ti nkan ko ba ti ṣenu ire fun Man U ninu ere bọọlu loun maa n ranti iya ti ọkọ oun tẹlẹ fi jẹ oun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Inyama sọ pe ‘’mo korira ẹgbẹ agbabọọlu Man United tori mo jẹ wabi-bọsu iya nigba kugba ti wọn ba ti fidi rẹmi.
Ti o fi di oni, ti Man U ba ti fidirẹmi ni mo maa n dupẹ lọwọ Ọlọrun ti mo si maa n sọ fun ara mi pe ajẹtun iya ni ko ba jẹ mi to ba jẹ pe mo si wa pẹlu ọkọ mi tẹlẹ ni.
Koda, ọmọkunrin mi gan an mọ, niṣe ni o maa n rẹrin.
Mo ranti ọjọ kan ti Man U fidirẹmi nini ifẹsẹwọnsẹ kan ti wọn gba, lẹyin naa ni ọkọ mi da ẹṣẹ bo ẹrọ amohunmaworan ti a n wo.
Ni mo baa beere wi pe ki ni a maa wo bayii, lẹsẹkẹsẹ ni o doju ija kọ mi pe ṣe baba lo ni ẹrọ amohunmaworan ọhun ni.
O ni ṣe baba mi lo gbe ẹrọ tẹlẹfisan naa wa ile ni, iyẹn lo jẹ ki n korira Man United di oni.''
Inyama pada fi ọkọ rẹ tẹlẹ silẹ nigba ti lulu pọju lẹyin to ni oun woo pe ẹmi oun le bọ ti oun ko ba fi ọkunrin naa silẹ.















