Èèmọ̀! Àwọn ajínigbé Zamfara jí ọkọ ìyàwó àti ìyàwó rẹ gbé lọ

Aworan afihan ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn janduku ajinigbe ti ji eeyan mẹrin gbe ni ipinlẹ Zamfara to fi mọ ọkọ iyawo ati iyawo ninu ikọlu oru mọju kan.

Ikọlu yi waye ni abule Madabanciya ni ijọba ibilẹ Bungudu ni ipinlẹ Zamfara.

Olugbe agbegbe naa kan sọ fun BBC pe awọn ajinigbe yii ko awọn nkan ọsin ati dukia salọ ti eyi si ṣokunfa bi awọn araalu ṣe sun sinu igbo tori ẹru awọn ajinigbe yi.

O ni pe: ''Ni nkan bi aago mejila kọja iṣẹgun mẹẹdogun ni awọn adigunjale ṣe ikọlu si wa ti wọn si ji eeyan mẹrin gbe.

Ọkunrin ati obinrin meji lo wa ninu wọn.

Wọn gbe ọkunrin kan ati iyawo rẹ gbe.

Awọn ni ọkọ iyawo ati iyawo rẹ''

Awọn alaburu yi tun ji awọn nkan ini iyawo to fi mọ aṣọ rẹ ti wọn si tun pa aja wọn.

Olugbe to ṣalaye ọrọ yi ni wọn ri gbogbo nkan wọnyi ṣe tori aisi aabo to peye lagbegbe naa.

Ọlọpaa Zamfara lawọn ko gburo nkankan

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aladugbo to ba BBC sọrọ sọ pe "Niṣe lawọn janduku to kọlu abule wa ri bi ṣọṣẹ tori pe ko si awọn agbofinro to n kaakiri lagbegbe naa.''

''Igba akọkọ ree tawọn ajinigbe yi to fi inu igbo ṣebugbe yoo tọ araalu wa.''

O ni ''Mi o mọ ibi ti wọn gbe ọkọ wọn si ati pe ọpọ ninu wọn lo gbe ibọn ti wọn n pe ni AK47 lọwọ ti wọn si n yinbọn soke.''

Awọn eeyan agbegbe naa sọ pe awọn ranṣẹ si awọn fijilante to wa lẹba wọn lati wa doola wọn.

''O ni agbegbe kan to wa ni Guusu Madabanciya ti wọn ti lawọn fijilante.

Nigba ti wọn gburo nkan to ṣẹlẹ, wọn wa lati wa ran wa lọwọ ṣugbọn awọn janduku yi ti lọ nigba ti wọn yoo fi de''

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Zamfara sọ pe awọn ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ yi.

ASP Yazid Abubakar to jẹ alukoro ọlọpaa sọ fun BBC pe aigburo nipa nkan to ṣẹlẹ jẹ ọkan lara idiwọ ti awọn n koju nidi iṣẹ wọn.

O ni idi ree ti iranwọ ko fi tete de si ọdọ awọn araalu lẹyin ti iṣẹlẹ yi waye.

"Iranwọ taa n beere lati ọdọ araalu ni pe ki wọn jẹ ki a mọ ti iru nkan bayi ba waye.

Kii ṣe pe ka ṣẹṣẹ maa wa gburo lẹyin ti iṣẹlẹ ba ti ṣẹlẹ kọja''

Tohun ti bi ijọba ṣe n polongo ifarajin wọn lati koju ipenija aabo to mẹhẹ ni apa iwọ oorun ariwa, awọn eeyan agbegbe naa n sọ pe niṣe lo n peleke si.