Ọmọọba ti ṣáájú lérí láti pa Adeoriokin tipẹ́ - Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Adeoriokin

Oríṣun àwòrán, Others
''Ọlọ́dẹ kọ́ ló pa Adeori Okin, jàndùkú Ọmọba Eniola Oyeyode ló yìnbọ pa á''
Arabinrin Abigael Idowu ẹni to jẹ iya fun Ologbe Richard Idowu Adeori Ọkin ti ẹṣọ ọmọba Ogiyan ilu Ejigbo ṣekupa sọ pe ogunna gbongbo nínú ẹbí ní Adeori Ọkin jẹ́, ''wọn sí gbá lọ́wọ́ mi.''
Arabinrin Idowu wa n beere fun idajọ ododo lori iku ọmọ rẹ Richard Idowu ti wọn yinbọn pa ni ọjọ Kẹtàdínlógún osu Kinni nile ọmọ Ọba Eniola Oyeyode nilu Ejigbo nipinlẹ Ọsun.
Mama oloogbe naa sọ pe, ori aisan rọpa-rọsẹ ni baba Idowu wa lati bi ọdun mẹjọ sẹyin, to si jẹ wi pe Adeori Ọkin naa lo ń se itọju baba rẹ.

Oríṣun àwòrán, Ade Ori Okin/facebook
Arabinrin Idowu ni ''mo fẹ ki gbogbo ọmọ orile-ede Naijiria ati awọn ijọba apapọ to fi de ti ipinlẹ ọsun ki wọn dide fun idajọ ododo lori ẹni to fi iku pa ọmọ mí.''
Afeez Lawal to jẹ amugbalẹgbẹ oloogbe sọ pe ''lati ́ọjọ kẹrindinlogun oṣu Keje ọdun 2022 ni ọmọ ọba Ogiyan ilu Ejigbo tí n fí ikú lé Ọga mí kiri.
Ọjọ Kẹrindinlogun osu Keje Ọdun 2022 to jẹ ọjọ idibo sipo Gomina nipinlẹ Ọsun ni ọmọ Ọba Eniola Oyeyode ti leri si Ọga mí wi pe oun yoo pa a tí ko si si ẹnikẹni ti yoo mu oun.
Lawal sọ pe ninu ẹgbẹ oselu APC ni Adeori Okin wa lasiko idibo sipo Gomina nipinlẹ Osun ni ọdun 2022, ṣugbọn ko pẹ tí ibo pari ni Ọga oun kuro ninu ẹgbẹ oselu APC lọ sinu ẹgbẹ oselu PDP.
''Ọga mi ni lọkan lati gbe apoti idibo fun ipo Asoju ipinlẹ ọsun ni Abuja ninu idibo miran to n bọ.
Bẹẹ ni ọmọ Ọba Eniola Oyeyode naa ní lọkan pẹlu lati dije pẹlu Ọga mi Adeori Ọkin ninu ẹgbẹ oselu kan naa.
Ọmọ ọba Eniola Oyeyode ko sọ fun Ọga mi pe ipade idakọnkọ yoo wa lẹyin ayẹyẹ aadọta ọdun ti baba rẹ pe lori apere awọn baba nla rẹ.
Ọga mi ti ṣe tan lati kuro loju agbo ti ayẹyẹ aadọta ọdun ti wọn n se, ṣugbọn Ọmọ ọba Oyeyode wi pe ki Ọga mí ko jẹ ka wọn ma lọ sile oun.
Nigba ti gbogbo wa de bẹ, ọmọ ọba Oyeyode kọ lati jẹ ka wọle, lẹyin ti wọn pari ipade naa tan ni a gbọ iro ìbọn to dun ninu ile, ti Ọga mi Adeori Ọkin si pariwo.
Ẹni to yinbọn pa Ọga mi ki i se ọlọdẹ rara, ara awọn janduku tí ọmọ Ọba Eniola Oyeyode mu kakiri lo yinbọn pa Ọga mi,'' Lawal lo sọ bẹẹ.
Amugbalẹgbẹ oloogbe naa wi pe, awọn fẹ idajọ ododo lori ẹni to pa ọga oloogbe ẹni ti gbogbo eeyan mọ sí Adeori Ọkin.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola sọ pe ofin ko faye gba ẹnikẹni lati ma yinbọn soke nibi kibi rara.
Arabinrin Opalola wi pe afurasi ọmọ ọba Eniola Oyeyode si wa ni kolo awọn fun iwadi to peye.
















