Ẹ ṣàwárí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé ní Ekiti kíákíá - Tinubu sáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò

Tinubu àti àwòrán àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/GETTY IMAGES

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ajínigbé ṣe jí àwọ akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ kan gbé ní ìpínlẹ̀ Ekiti lọ́jọ́ Ajé.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ààrẹ, Ajuri Ngalele fi síta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ní Tinubu dárí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣàwárí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ náà ní kíákíá.

Tinubu pàṣẹ pé kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ri dájú pé wọ́n ṣàwàrí àwọn ènìyàn náà láàyè, kí wọ́n sì nawọ́ gán àwọn oníṣẹ́ ibi tó wà nídìí ìjínigbé ọ̀hún.

Ó ní ojúṣe ìjọba ni ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn, tó sì sọ àrídájú rẹ̀ pé àtúntò bá ẹ̀ka ètò ààbò Nàìjíríà, kí àwọn ènìyàn le sùn fi orí lé òṣùká.

Bákan náà ló ní àwọn máa ró àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ní agbára kí wọ́n le ṣe ojúṣe wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Ajínigbé jí akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà, olùkọ́ mẹ́ta gbé lásìkò tí wọ́n ń padà sílé ní Ekiti

Àwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà àti olùkọ́ mẹ́ta ilé ẹ̀kọ́ kan gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Emure, ìpínlẹ̀ Ekiti.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní ọdún 2024 ni ìjínigbé náà wáyé nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ náà ń padà sílé wọn.

Àtẹ̀jáde kan tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti fi sórí ayélujára lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Biodun Oyebanji wá rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà láti fọkàn balẹ̀ pé ìjọba ti ń gbé ìgbésẹ̀ akin láti ri dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà padà sílé wọn láyọ̀ àti àláfíà.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ náà ń padà sí Eporo-Ekiti pẹ̀lú ọkọ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà ni ọjọ́ Ajé kí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé náà tó wáyé.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Gómìnà Oyebanji tó júwe ìjínigbé náà bí ìwà ọ̀dájú àti ohun tí kò bá etí mu eárá ní gbogbo ipá àwọn ni àwọn máa sà láti ri pé wọ́n gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ ní kíákíá.

Ó ní gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà ní ìpínlẹ̀ Ekiti ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ láti tọpasẹ̀ àwọn ajínigbé náà kí wọ́n sì fi wọ́n jófin.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò nípa fífún wọn ní àwọn ìròyìn tó bá yẹ tàbí tí wọ́n bá kẹ́fín ohun àjòjì ní agbègbè wọn.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn jọ kò ì tíì sí ikọ̀ kan tó jáde láti sọ pé àwọn ni wọ́n wà nídìí ìjínigbé náà.

Bákan náà ni àwọn ajínigbé náà kò ì tíì pè láti bèèrè fún owó ìtúsílẹ̀.

Ìjínigbé láti fi bèèrè fún owó ti ń paléke si láti bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.