Wọ̀nyí làwọn àdéhùn mẹ́sàn-án tí Ààrẹ Tinubu buwọ́lù ní Türkiye àti ipa tí yóò ní lára Naijiria

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga
Ninu igbiyanju rẹ lati mu eto ọrọ aje, eto aabo, igbaye-gbadun ati bẹẹ bẹẹ lọ waye fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni Aarẹ Bola Tinubu ṣe tẹkọ leti lọ si orilẹede Türkiye, eyi ti olu ilu naa jẹ Ankara.
Ọjọ Iṣẹgun ana ni irinajo naa han si awọn eeyan miran ti ko kọbi ara si i tẹlẹ, ohun to si fa a ni bi Aarẹ Tinubu ṣe yọ to si ṣubu laaarin awọn eeyan niluu naa.
Eyi ni ọpọ eeyan ri lori ayelujara ti wọn si bẹrẹ si I sọrọ nipa rẹ.
Bawọn kan ṣe n sọ pe agba lo n da Aarẹ Naijiria laamu, ni awọn miran n sọ pe eyi kọ ni igba akọkọ ti Aarẹ yoo ṣubu.
Bẹẹ ni awọn miran n sọ pe ọrọ Naijiria ni Tinubu ko sokan to bẹẹ, to fi gbera gba Turkey lọ, ati pe ka ki I, ka si yin in fun iṣẹ takun-takun to n ṣe ki Naijiria le ṣẹgun awọn iṣoro rẹ.
Ṣugbọn ni ti ododo, Aarẹ Tinubu ko ba awẹwa lọ silẹẹ Türkiye, adehun onikoko mẹsan lo tọwọ bọwe rẹ pẹlu Aarẹ orilẹede naa ti i ṣe Recep Tayyip Erdogan, lọjọ Iṣẹgun ana.
Awọn adehun mẹsan-an naa ree

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga
Nibi ipade oniroyin to waye lẹyin iṣẹlẹ to gbe Aarẹ Tinubu jade, o ṣe awọn ojuṣe to tori ẹ wa niluu naa, koda, ileeṣẹ Aarẹ ilẹ wa fi atẹjade sita pe ṣaka ni ara Aarẹ da, kinni kan ko mu un lẹyin iṣubu naa.
Oludamọran pataki fun Aarẹ Tinubu lori ikede, Bayo Onanuga, kede pe idokowopọ ti ko din ni biliọnu marun-un owo dọla ($5billion) ni Aarẹ ilẹ Turkiye, Erdogan, n foju sọna si lati ba Naijiria ṣe.
Awọn adehun yoku ni :
- Adehun lori ofin to de ọrọ ilẹ okeere.
- Adehun lori idaaabo bo ara ẹni.
- Ipinnu lati tun ọrọ aje ṣe ati yiyan igbimọ papọ.
- Ipese awọn nnkan amayedẹrun to jẹ ojulowo.
- Ifọwọsowọpọ lẹka ẹkọ giga.
- Ifọwọsowọpọ lẹka iroyin ati ibaraẹnisọrọ
- Ifọwọsowọpọ lẹka ẹkọ.
- Ifọwọsowọpọ laarin ilẹ Olominira Türkiye, ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere pẹlu ijọba apapọ Naijiria, ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin, idagbasoke awujọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ipa ti awọn nnkan yii yoo ni lara Naijiria
Gẹgẹ bi alaye Aarẹ ilẹ Turkiye, Recep Erdogan, o ni anfaani tuntun ni ajọṣepọ ilẹ naa pẹlu Naijiria yoo mu ba orilẹede wa.
Yoo tun mu ki idokoowo Turkey gbooro si I ni Naijiria.
O ni ajọṣepọ naa yoo mu ki $5 billion ti afojusun wa fun wa si imuṣẹ lẹka idokowo.
Bakan naa ni yoo mu ẹka aabo dara si i.
Erdogan ṣaleri atilẹyin fun Naijiria lati gbogun ti igbesunmọmi, paapaa lawọn apa Sahel.
Bakan naa lo ni ajọṣepọ yii yoo mu ki esi rere wa lati ẹka epo rọbi Naijiria.
Itẹsiwaju yoo ba ẹka ẹkọ paapaa bo ṣe wi, bẹẹ ni awọn eeyan yoo le da duro ni abala idagbasoke ti wọn ba yan.
Aarẹ Tinubu ninu alaye rẹ, sọ pe Naijiria yoo maa tẹsiwaju lati gbe alaafia ga, bẹẹ ni ilẹ Africa yoo duro giri, bo tilẹ jẹ pe idojukọ eto aabo wa fun un.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe eyi ko dun mọ ẹnikẹni lati royin, ṣugbọn eegun to ba ti jade ti kuro ni a ki I wo o.
Nibi awọn eto ita gbangba lorilẹede yii, Aarẹ Tinubu ti ṣubu ri ti kamẹra si gbe e, to kari ayelujara.
Akọkọ iru iṣẹlẹ bẹẹ ni eyi to waye nipinlẹ Kaduna loṣu kẹta ọdun 2021, lasiko to n ṣọna lati di aarẹ Naijiria nigba yẹn.
Ilu Abuja ni iṣubu keji ti waye, ni 2024.
Ayẹyẹ ọdun kẹẹẹdọgbọn ijọba awarawa ni Naijiria n sami rẹ lọjọ naa, ti ẹsẹ Aarẹ Tinubu fi tase akasọ kan to si ṣubu ni gbagede Eagle Square, niluu Abuja.
Aarẹ fi ọrọ naa dapara lẹyin-o-rẹyin, o ni ọmọ ibilẹ Yoruba loun, oun dọbalẹ bii ikini abinibi ni.
Iṣubu ẹlẹẹkẹta si ni ti Turkey to n ja ran-in nilẹ lọwọ, to waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.
Awọn aarẹ to ti ṣubu ni gbangba ri
Iṣubu ko kan ẹya, bẹẹ ni ko kan ọjọ ori tabi ipo ti eeyan wa, ẹni to ba ti jẹ ẹlẹran ara le ṣubu lai ri ọgbọn da si i.
Wọnyi lawọn aarẹ to ti ṣubu ni gbagede aye ri yatọ si Tinubu
1. Joe Biden (USA): O ṣubu lasiko to fẹẹ wọ baaluu ni 2021.
2. Vladimir Putin (Russia): Nigba to n ṣere idaraya lorii yinyin lo ṣubu ni 2019.
3. Emmanuel Macron (France): Okun kan lo kọ ọ lẹsẹ, o si ṣubu lasiko abẹwo rẹ si ileeṣẹ kan ni 2020.
4. Boris Johnson (UK): O ṣubu sinu omi lasiko to fẹẹ fo omi to darogun kan ni 2019.
5. Muhammadu Buhari (Nigeria): O ṣubu lasiko to n sọkalẹ ninu ọkọ ni 2017.
6. Donald Trump (USA): O yọ ṣubu nigba to fẹ wọ ọkọ ofurufu ologun ni 2017.
7. Jacob Zuma (South Africa): O ṣubu lasiko to fẹẹ gun ori itage lati sọrọ ni 2015.
8. Abdel Fattah el-Sisi (Egypt): Waya kan lo kọ ọ lẹsẹ to fi ṣubu lasiko eto awọn ologun kan ni 2014.

Oríṣun àwòrán, Anadolu via Getty Images
Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti sọ pe ṣaka lara Aarẹ Bola Tinubu da lẹyin ti aarẹ yọ ṣubu niluu Ankara lasiko to n ṣabẹwo si orilẹede Turkey lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kinni ọdun yii.
Fidio kan to lu ori ayelujara pa ṣafihan bi Aarẹ Tinubu ṣe yọ ṣubu nigba to n rin lọ pẹlu Aarẹ Tayyip Erdoğan orilẹede Turkey lasiko ayẹyẹ ikini kaabọ ti wọn ṣe fun un.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n kọminu lori ilera aarẹ lẹyin to tun yọ ṣubu ni Turkey.
Amọ, oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, ti ṣalaye pe koko lara Tinubu le bi ọta.
Onanuga ṣalaye pe Aarẹ Tinubu ṣadeede tẹ nnkan mọlẹ lo jẹ ko yọ ṣubu.
''Aarẹ ṣee si tẹ nnkan mọlẹ ni lo jẹ ki o yọ, nnkan to ṣẹlẹ kii ṣe ohun to lagbara rara.
Bi aarẹ ṣe yọ kii ṣe tuntun, ayafi awọn to ba fẹ fikun nnkan to ṣẹlẹ loku.
Tinubu kan yọ ni, a dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe ko ṣubu,'' Onanuga ṣalaye
Oludamọran aarẹ ni Tinubu ko ni ipalara kankan, o si tẹsiwaju pẹlu eto to lọ ṣe lorilẹede Turkey.
Awọn alabaṣiṣẹpọ aarẹ to kọwọọ rin pẹlu rẹ lọ si orilẹede Turkey ti sọ pe nnkan to ṣẹlẹ ko ni ipa ti ko dara lori eto ti aarẹ ba lọ si Turkey.
Wọn ni Tinubu ti ṣe oniruuru ipade pẹlu ijọba orilẹede Turkey eyi ti yoo jẹ ki ibaṣepọ laarin Naijiria ati Turkey tun gbopan si i.
Awọn oludamọran aarẹ tun sọ pe awọn ipade ti aarẹ n ṣe pẹlu ijọba Turkey yoo tun jẹ ki ọrọ aje Naijiria gberu si i.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















