Bàbá tó bí agbábọ́ọ̀lù Super Eagles, Wilfred Ndidi, jade láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sunday Ndidi, to jẹ baba to bi agbabọọlu Super Eagles, Wilfred Ndidi, ti jade laye lẹyin ijamba ọkọ kan nipinlẹ Delta.
Oloogbe ọhun, to jẹ ajagunfẹyinti lo ku lẹyin ijamba ọkọ naa to waye niluu Umunede lọjọ iṣẹgun.
Wọn tete gbe lọ sile iwosan kan niluu Agbo lẹyin ijamba naa amọ lẹyin ti wọn gbe debẹ lawọn dokita kede pe ẹlẹmi ti gba a.
Ẹgbẹ agbabọọlu ti Ndidi n gba bọọlu fun lorilẹede Turkey, Beşiktaş, ti ba agbabọọlu naa kẹdun.
Ninu atẹjade kan ni ẹgbẹ agbabọọlu ọhun ti sọ pe awọn ba oun ati gbogbo idile rẹ kẹdun iku baba rẹ ọhun.
Ajọ to n ri si bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF, naa ti ba Ndidi kẹdun iku baba rẹ.
NFF sọ pe iku oloogbe naa jẹ eyii to ba oun lọkan jẹ paapaa lẹyin bi ọmọ rẹ ṣe ṣiṣẹ takuntakun fun Naijiria ninu idije bọọlu ilẹ Afrika, Afcon 2025, ti wọn ṣẹṣẹ pari ni Morocco.
Lẹyin naa ni wọn gbadura ki Eledua tu agbabọọlu ọhun ati gbogbo mọlẹbi rẹ ninu.
Ẹnu lọlọ yi ni Ndidi ṣẹṣẹ di baale ikọ Super Eagles, lẹyin ti William Troost-Ekong kede pe oun ti fẹyinti.
Labẹ iṣakoso Ndidi ni ikọ agbabọọlu Naijiria ti ṣaṣeyọri ipo kẹta ninu idije Afcon to waye ni Morocco loṣu Kejila ọdun to kọja si ibẹrẹ ọdun 2026 yii.
Lasiko idije naa ni Ndidi sọrọ rere nipa baba rẹ ati agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Nwako Kanu gẹgẹ bii iwuri fun ajọyọ goolu ti oun sọ sinu awọn Tunisia.
Ọpọ awọn ololufẹ Ndidi kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n fi ọrọ ibanikẹdun ṣọwọ si.














