Irọ́ ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé l'Ekiti ti gb'òmìnira

Irọ ni iroyin kan to sọ pe awọn ajinigbe ti fi awọn akẹkọọi ile ẹkọ Apostolic Faith Montessori School, Emure Ekiti silẹ.
Iroyin naa lo tan kalẹ lori ayelujara lale ọjọ Ẹti pe awọn ajinigbe ti tú àwọn ọmọ ile ẹkọ naa silẹ leyin ọjọ mẹrin ni akata wọn.
Nigbati BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn osise ile ẹkọ naa, oṣiṣẹ ọhun ti ko fẹ ki a da orukọ oun fidi rẹ mulẹ pe irọ tí ojina sì otọ ni iroyin naa.
O tesiwaju pe lootọo ni ariwo ayọ sọ ninu ilu Emure-Ekiti ti o si de inu ọgba ile ẹkọ naa, eyi lo mu ọgọrọ ero salo afin Kabiyesi ti Emure-Ekiti lati ri aridaju boya otitọ ni.
Bakan naa ni agbenuso fun gomina ipinle Ekiti lori eto iroyin, Ọgbeni Yinka Oyebode tun fidi rẹ mule pe irọ nla ni iroyin naa pe ijoba ko gbo ohun ti o jọ bẹ.
Awọn eleto abo naa si tun fi idi rẹ mule pe awọn eso alabo n ṣe isẹ takuntakun lati ri pe awọn ọmọ naa pada si ile layo ati alafia.











