Gani Adams: Ìṣòro ètò aàbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ Yorùbá, oṣù mẹ́fà péré ní máa fí kojú rẹ̀

Aworan Gani Adams

Oríṣun àwòrán, @OODUAGRAPHICS

Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba Iba Gani Adams ti ṣeleri lati mu opin ba ipenija aabo to n koju ilẹ Yoruba laarin oṣu mẹfa pere.

O fidi ọrọ yi mulẹ lasiko ajọdun Oodua Festival eleyi ti Olokun Festival Foundation ṣe agbatẹru rẹ.

Nibi ayẹyẹ taa n wi yi bakan naa ni Ooni Ife Oba Adeyeye Ogunwusi ti sọ pe oun yoo ṣa gbogbo agbara lati ri wi pe awọn Gomina ipinlẹ Yoruba buwọlu ikopa Gani Adams nibi amojuto eto aabo nilẹ kaarọ o jiire.

Oba Idowu Adediwura to ṣoju Ooni fikun pe ''asiko ti to bayi lati lo nkan to ba wa ni ikapa wa lati le ri nkan taa n fẹ.A fẹ ṣeto aabo to peye nibi idaabo ẹmi ati dukia wa.A fẹ fẹdọ lori oroonro a si ni eeyan ti yoo ba wa ṣe amuṣẹ rẹ''

Ninu ọrọ rẹ ni idahun nibi ayẹ yi, Iba Gani Adams sọ pe agbarijọpọ ero ni ọna abayọ lati koju ipenija aabo to n da ilẹ Yoruba laamu.

O fi da awọn Gomina ipinlẹ Yoruba loju pe ti wọn ba file faaye gba oun lati kopa ninu eto aabo,laarin oṣu mẹfa nkan yoo fi pada si daad.

''Gẹgẹ bi aarẹ Ona Kakanfo a ko ni faaye gba nkan to n ṣẹlẹ ni Plateau ti wọn ti pa eeyan ni ipakupa lati waye ni ilẹ Yoruba kankan''

O ni pẹlu ipenija aabo ti Naijiria n koju bayii, o ti han gbangba pe ijọba ko ni ikapa nikan lati koju rẹ.

Ni Naijiria ilẹ oni to mọ ipenija aabo ti wa di nkan ti gbogbo araalu n ran lẹnu.

Yala ni ilẹ ariwa ni tabi ni ilẹ Yoruba ọrọ yi ko yọ ẹnikankan silẹ.

Laipẹ yi ni awọn ajinigbe agbebọn ṣe ikọlu si awọn oriade kan ni ipinlẹ Ekiti ti wọn si ṣeku pa wọn.

Bakan naa ni a tun ṣẹṣẹ n gbọ iroyin pe awọn ajinigbe pa Kabiyesi kan ni ilu Koro Ekiti ni ipinlẹ Kwara ti wọn si ji olori rẹ ati awọn eeyan mi salọ.

Titi di ba ṣe n ko iroyin yi jọ wọn ko mọ ibi tawọn ajinigbe yi poora si.

Ọna wo ni Gani Adams fẹ gbe ọrọ yi gba

Nibi ayẹyẹ ti ọrọ yi ti jẹyọ, Gani Adams ko sọ pato bi oun ṣe fẹ koju ipenija aabo yi ju pe oun yoo fẹ ifọwọsowọpọ ijọba alaabo ati araalu.

Gani Adams jẹ ilumọoka lori ipa ti Oodua Peoples Congress to da silẹ ko nibi ipese aabo nigba kan ri ni Naijiria.

Lasiko ti wọn wa loju ọpọn, orukọ OPC a maa dẹru ba awọn ọdaran amọ aṣemaṣe kọọkan nipa aṣilo agbara mu ki ijọba koro oju si ikọ yi.

Lẹnu lọọlọ yi, Gani Adams ti n polongo pe ki awọn ijọba ipinlẹ Yoruba ṣamulo awọn ikọ OPC lti le koju ipenija aabo to mẹhẹ.

Titi di asiko yi awọn Gomina ko ti fẹsi si ọrọ yi boya tori pe wọn ni ikọ alaabo ti wọn da silẹ taa mọ si Amotekun.

Amotekun yi naa n ṣapa wọn amọ ai si agbara to to agbara ko jẹ ki wọn le ṣe iṣe aabo naa bo ti ṣe yẹ.