Ọwọ́ ẹ̀ṣọ́ aàbò 'Safe Corps' tẹ Ojúgbélẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìjínigbé l’Ógùn

Oríṣun àwòrán, Ojugbele/So-Safe Corps
Ileeṣẹ eleto aabo nipinlẹ Ogun ti a mọ si Social Orientation and Safety Corps, iyẹn So-Safe Corps ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin kan, Ojugbelẹ Joshua lori ẹsun ijinigbe.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ So-Safe Corps, Mọruf Yusuf gbe sita, eyi to fi ranṣẹ si BBC YORUBA, o ni Ojugbelẹ wa lara awọn ajinigbe to ji ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan gbe lagbegbe Ọlọrunṣogo, Ọlọrunda, ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.
Yusuf sọ pe ni nnkan bi aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹẹdogun, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn ji ọmọdekunrin naa gbe lasiko to lọ tọ lẹyinkule ile baba rẹ.
Siwaju sii lo sọ pe baba ọmọ ọhun, Ọgbẹni Sunday Iboin lo wa fi to awọn leti lọjọ keji, ọgbọn ọjọ, oṣu kinni, ọdun 2024.
O ni baba naa sọ pe ọmọ oun jade si eyinkule ile wọn lati tọ lalẹ ọjọ naa ni, ko to di pe ko pada wọle lati sun.
Lẹyin bi iṣẹju marun-un ti ọmọ naa ko pada wọle lo mu ki baba rẹ jade sita lati wo o, ṣugbọn ti ko rii, latigba naa lo ti bẹrẹ sii pe foonu rẹ, ti ko sẹni to gbe.
Igba to ya lo sọ pe ẹnikan gbe foonu naa, to si n beere miliọnu kan ataabọ naira lọwọ rẹ lati fi gba ọmọ rẹ silẹ.
Yusuf ni Sunday fura si ọkan lara awọn ara adugbo lati mọ nipa bi wọn ṣe ji ọmọ rẹ gbe, to si eyi lo mu ki wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii.
Gbogbo inu igbo to wa lẹyinkule ile ti wọn ti ji ọmọ naa gbe ni Yusuf sọ pe awọn ẹṣọ aabo wọn fọ, lati rii gba jade, to si ni aṣeyọri pada waye.
Yusuf fi kun ọrọ rẹ pe aṣiri awọn ajinigbe ọhun tu nibi ti wọn fi ṣe buba, ti wọn si ri ọmọ naa gba jade, ṣugbọn to ni awọn mẹta to wa nidi iṣẹ buruku naa salọ.
Ninu iwadii lo sọ pe ọwọ ti tẹ Ojugbelẹ, to si lo ti jẹwọ pe lotitọ loun mọ nipa bi wọn ṣe ji ọmọ naa gbe, ati pe awọn mẹta ni wọn wa nidi ijinigbe ọhun.
Yusuf wa jẹ ko di mimọ pe awọn ti lọ fa Ojugbelẹ le awọn ọlọpaa ẹkun Imala lọwọ lati le tẹsiwaju iwadii wọn, ati lati fi ọwọ ofin mu.












