Ọ̀wọ́ngógó Dọ́là ní Nàìjíríà, àwọn Oníṣòwò 'Bureau de change' dáwọ iṣẹ́ dúró ní Abuja

Ẹka awọn oniṣowo paṣiparọ owo taa mọ si Bureau de Change to wa ni Abuja,olu ilu Naijiria ti kede pe awọn yoo dawọ iṣẹ duro.
Idi ti wọn lawọn fẹ tori rẹ ṣe bẹẹ ni ọwọngogo dọla to gbode.
Ninu fọnran fidio kan ti alaga ẹgbẹ naa ti ba BBC Hausa takurọsọ, ọgbẹni Abdulahi Dauran sọ bẹrẹ lọjọ Kini oṣu Keji ọdun 2024 ni awọn ko ni ṣiṣẹ.
O ṣalaye pe ọwọngogo dọla yi ko jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ oniṣowo paṣiparọ owo yi ri iṣẹ wọn ṣe bo ti ṣe yẹ.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Ninu alaye rẹ, o ni ọwọngogo yi ko ṣẹyin bawọn kan ṣe n ṣe idokoowo loju opo ayelujara ati bi idokowo crypto ti ṣe gbode lagbo idokoowo.
O ni awọn iṣẹlẹ wọnyi lo mu ki iye dọla taa n foju ri kere si ju ti tẹlẹ lọ to si n ṣakoba fun awọn to n ṣowo rẹ loju aye.

Oríṣun àwòrán, Getty
Kini CBN ti ṣe?
Laipẹ yi ni banki apapọ Naijiria gbe awọn igbesẹ kọọkan lati fi fagbara fun Naira loju agbami ti dọla ti n tẹ ẹ ri.
Lara rẹ ni ṣiṣi aaye silẹ ki onikaluku maa ta dọla ni iye to ba ba de ọdọ wọn loju opo kan ṣoṣo ti ọlọja ati alabara yoo ti maa ta dọla ni iye ti ọja ba tọka si.
Eyi wa lara ipinnu aarẹ Bola Tinubu ninu ọrọ to ba araalu sọ lasiko ti wọn bra wọle sipo fun.
Ni igba taa n wi yi, iye owo paṣiparọ dọla si Naira ni oju oṣunwọn ti ijọba wa ni nkan bi ₦460 si dọla kan.
Loju opo tawọn oni paṣiparọ bureau d change, iye Naira si dọla si jẹ ₦750.
Nilẹ toni to mọ, ọrọ naa ti buru kọja tatẹyinwa ti awọn kan si n ta Naira ni ₦1,460 ni paṣiparọ dọla kan.















