Mi ò kí ń ṣe aláwàdà, ipá tó fi mí hàn ni àwọn èèyàn fi máa ń rò pé aláwàdà ni mí - Portable Harejan
Mi ò kí ń ṣe aláwàdà, ipá tó fi mí hàn ni àwọn èèyàn fi máa ń rò pé aláwàdà ni mí - Portable Harejan

Èèkàn òṣèré tíátà nnì, Muhammed Lukman Olowogemo Harejan Harejan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ lórí bí ìrìnàjò rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ nídìí iṣẹ́ eré tíátà.
Portable ṣàlàyé pé eré tíátà dàbí àjẹbí fún òun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òun òbí òun kò ṣe iṣẹ́ tíátà.
Ó ní ìbátan ni òun àti Ebun Oloyede tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Olaiya Igwe àti pé ara rẹ̀ ni òun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí òun yàn láàyò.
Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpèníjà tó ti là kọjá àti èyí tó ń kojú lọ́wọ́ nínú eré tíátà.
Bákan náà ló sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ tíátà lóde òní.






