Náírà sí Dọ́là: Tinubu ní láti fòfin de irun wíìgì ti wọ́n n kó wọlé sí Nàíjíríà – Reno Omokri

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri/Aare Bola Tinubu/Instagram
Amugbalẹgbẹ aarẹ tẹlẹ, Reno Omokri ti gba Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lamọran lati fi ofin de bi wọn ṣe n ko irun ilẹ okere wọle si Naijiria.
Reno Omokri lo sọrọ yii lori ikanni ayelujara ti ‘X’ rẹ laipẹ yii, to si ni irun ti wọn n ko wọle si Naijiria jẹ ọkan pataki lara awọn ohun to n ṣakoba fun owo naira.
O ni bi Tinubu ba fi ofin de awọn ẹru ti wọn n ko wọle, yoo din iṣoro to n koju owo naira ku patapata.
Bẹẹ lo sọ pe awọn ọmọ Naijiria funra wọn pẹlu iṣoro to n koju owo naira.
Omokri to ti figba kan ri jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Ebele Jonathan sọ pe aami idanimọ nla owo naira jẹ fun Naijiria.
Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọmọ Naijiria ṣe fẹran lati maa wọ awọn baluu ilẹ okeere, ti wọn si n kọ baluu Naijiria silẹ lati maa fi rin irin ajo wọn.
“Ẹ wo o, banki apapọ Naijiria ṣẹṣẹ san biliọnu owo dọla fun awọn baluu ilẹ okeere. Oju ọna kan naa ni awọn baluu wọnyi n fo pẹlu baluu Air Peace.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Okri tun sọ pe: “Njẹ ẹ mọ pe bi emi ati iwọ, gẹgẹ bi ọmọ Naijiria ba n lo baluu Air Peace dipo ti ilẹ okeere, biliọnu kan dọla naa yoo duro ni Naijiria lati kari.
“Bi owo dọla ati pọun ba n duro ni Naijiria, owo Naira yoo maa dide lati lagbara. Bi wọn ba kuro ni Naijiria, owo naira wa yoo maa lọ silẹ.
“Banki apapọ Naijiria tun wa ni lati maa pọ igba miliọnu owo dọla lati maa fi san owo irun eeyan, bi ẹni pe Ọlọrun ko fun awọn obinrin wa ni irun.
“Awọn irun yii ni awọn obinrin Indian, Bangladeshi, ati Southeast Asian ge danu lati fi jin fun awọn oriṣa wọn.
“Lẹyin eyi, wọn a wa ko irun naa jọ, wọn a fun un ni orukọ bii ‘Brazilian, European ati Peruvian hair’, awọn obinrin wa yoo si maa sare lọ ra wọn.
“Wọn a wọ ọ sori, wọn a tun maa mi irun naa lati fi bu ẹnu atẹ lu Tinubu wi pe oun lo n ba eto ọrọ aje jẹ.
“Bi mo ba jẹ Tinubu ni, mo maa fi ofin de kiko irun eeyan wọle si Naijiria. Ẹ lọ ṣe iwadii, gẹgẹ bi orileede, Naijiria n na owo to pọ lori irun eeyan ju iwe lọ.
“Awọn kọntena to n gba ori agbami okun wọle si Naijiria pẹlu awọn ohun ti a le pese funra wa lo n pa owo Naira...”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












