Darasimi Omoseyin rí ẹ̀wọ̀n he nítorí pé o tẹ owó náírà mọ́lẹ̀ lójú agbo lẹ́yìn tó ṣe náírà báṣubàṣu

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
Ile-ẹjọ giga apapọ to wa lagbegbe Ikoyi, ipinlẹ Eko ti ju oṣerebinrin nni, Oluwadarasimi Ọmọṣẹyin sẹwọn oṣu mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun ṣiṣe owo naira baṣubaṣu lode ariya.
Onidajọ Chukwujekwu Aneke lo gbe idajọ ọhun kalẹ l’Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejidinlogun, oṣu kinni, ọdun 2023 ni Oluwadarasimi lọ sode ariya kan to waye ninu gbọngan ayẹyẹ Monarch (Monarch Event Centre) to wa ni Lekki, ipinlẹ Eko.
Ọjọ keji ayẹyẹ ọhun ni fọnran Oluwadarasimi jade sori ikanni ayelujara nibi to ti n na owo ninakuna loju agbo, to si tun n tẹ owo ọhun mọlẹ, eyi to mu ki awọn ọmọ Naijiria maa sọ oriṣiriṣi nipa ẹ.
Ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2023 ni ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati jibiti lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti kọkọ wọ Oluwadarasimi lọ siwaju ile-ẹjọ.
Ẹsun meji ọtọọtọ ni ajọ EFCC fi kan an ni abala kọkanlelogun, ipin kinni ninu iwe ofin banki apapọ ti ọdun 2007, bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Lọjọ kẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 2023 ni ile ẹjọ ni anfaani wa lati gba beeli.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Aneke sọ pe awọn ẹri toun ri gba kọja ohun ti wọn le fọwọ bo mọlẹ, to si ni afi ko lọ fi ẹwọn oṣu mẹfa gbara lati le fi kẹkọọ nipa bi o ṣe gbọdọ maa bọwọ fun owo naira.
Ṣaaju asiko yii ni agbẹjọro Oluwadarasimi ti rọ ile ẹjọ lati boju aanu wo, nitori to sọ pe akọkọ ree ti onibara oun yoo ṣẹ ẹṣẹ naa, ati pe iya ọlọmọ kan to ti gba pe oun jẹbi ni, to si ti bẹbẹ.
Ju gbogbo rẹ lọ, Onidajọ Aneke wa sọ pe anfaani wa fun Oluwadarasimi lati san owo itanran, ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, iyẹn bi ko ba fẹẹ lọ sẹwọn.












