Pẹlumi Nubi rèé ọ̀dọ́bìnrin tó tí ǹ wa mọ́tò bọ̀ láti London wá sí Nàìjíríà

Aworan Pẹlumi Nubi/Instagram

Oríṣun àwòrán, Pẹlumi Nubi/Instagram

Pupọ awọn to ti gbọ iroyin nipa ọdọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Pẹlumi Nubi to fẹ ẹ wa ọkọ lati ilu London wa si Naijiria lo n ṣe wọn ni kayeefi.

Igba akọkọ ree ti obinrin yoo gbe iru igbesẹ bayii kaakiri agbaye.

Odu ni Pẹlumi, kii ṣaimọ foloko nibi ka rin irin ajo afẹ ti ko wọpọ, to si ti lọ kaakiri orileede ti ko din ni ọgọrin lagbaye.

Igba wo ni Pelumi ṣe ipinnu yii?

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọdun kan ati oṣu diẹ sẹyin ni Pẹlumi ti n gbaradi lati gbe igbesẹ akikanju yii.

Ọpọ iwadii ni Pẹlumi ti ṣe lori ki irin ajo yii le ni aṣeyọri, bẹẹ lo ti fọrọ wa awọn to ti rin iru irin ajo bayii lẹnu wo, lati mọ iriri wọn.

Nigba to n sọrọ, Pẹlumi sọ pe ọkan kii balẹ nigba toun ba ranti nipa igbesẹ yii, ṣugbọn to maa tun gbe ọkan rẹ kuro wi pe ko sohun ti ko le ṣẹlẹ bi eeyan ba ti ni igboya.

Kini Pelumi fi gbaradi?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara awọn igbaradi ti Pẹlumi ṣe ni pe, o lọ ṣe ọkọ rẹ ni eyi ti yoo mu ki irin ajo rẹ rọrun.

Ninu ọkọ naa, aaye idana ounjẹ, aaye ibusun, aaye ifọbọ ati ifọsọ wa nibẹ pẹlu.

“Mo ti n palẹmọ lati bi ọdun kan le diẹ sẹyin, mo ti ba awọn to ti rin iru irin ajo bayii sọrọ lati mọ iriri wọn ati awọn iṣoro ti wọn la kọja. Mo tunm ti ṣe awọn iwadii kun iwadii lori igbesẹ ti mo fẹẹ gbe yii.

“Mo ti lọ ṣe iwadii iye ti yoo na mi lati rin irin ajo yii, ati awọn ọna ti maa gba, to fi mọ bi maa ṣe gba awọn ilu ati orileede kan kọja, bẹẹ ni mo tun ti ṣe iwadii awọn ọna to dara lati rin nitori eto aabo.

“Abẹlẹ ni mo ti n ṣe awọn iwadii wọnyi. Igba miran maa fẹ pariwo ara mi sita, igba miran ọkan mi ko tun ni balẹ lori irin ajo yii.

“Ṣugbọn nigba miran mo maa n rii pe nnkan to ṣee ṣe ni, nnkan to si le ṣẹlẹ ni, ohun ti mo si fẹ ki awọn eeyan mọ gan-an niyẹn wi pe ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ laye yii.

“Eleyii yatọ, bo tilẹ jẹ pe mo ti ṣe awọn kekeeke kan sẹyin, ṣugbọn eyi ti mo dawọ le

Nibo ni Pelumi ti de bayii?

Eyii tun lagbara ju awọn ti atẹyinwa lọ. Eleyi maa gba asiko, bẹẹ lo si maa gba owo to pọ diẹ.

“Mo ti rin irin ajo lo si awọn orileede to yatọ si ara wọn, bi a ba si ni ka wo o, ko din ni orileede mẹtadinlogun ti mo maa gba kọja ko to di pe mo de ilẹ Afrika ti mo n lọ.

“Kii ṣe pe ki n wa ọkọ nikan, mo tun fẹẹ ni iriri nipa awọn orileede ati ilu ti mo ba n de ninu irin ajo yii. Diẹ ninu awọn ilẹ Yuroopu ko to di pe mo sọda si orileede Morocco.

“Bẹẹ si ni maa rin in titi dẹ Guusu ilẹ Afrika.

“Fun emi, mo fẹẹ rin rin ajo yii lati jẹ ki awọn to ri bi mo ṣe ri yii mọ pe ko si nnkan ti ko le ṣẹlẹ, ati lati jẹ ki awọn to ba tun fẹẹ rin iru irin ajo yii le mọ pe anfaani wa fun wọn.

“Mo fẹẹ fi mu awọn eeyan lori wu, ki inu wọn le dun pe ọmọ kekere bii temi gbe igbesẹ akikanju.

“Mo si tun fẹẹ ṣakifihan ilẹ Afrika ni ọna ti ẹnikẹni ko tii ṣe ri laye.”

Pelumi ti gbera ni London o si ti n bọ wa si Naijiria diẹdiẹ bayii