Mọ̀ síi nípa bí aàrùn ẹ̀tẹ̀ ṣe ń tàn káàkiri àgbáyé

Aworan ẹni to ni aarun ẹtẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Aarun ẹtẹ jẹ ọkan lara awọn aarun lawọn orileede agbaye ti o sunmọ ibi ti oorun ti n mu pupọ.

Tohun ti igbiyanju ijọba ati awọn ẹgbẹ ọlọdanni lati koju aarun yi, akọsilẹ fi han pe niṣe lo n peleke si ti itọju aarun yi ṣi jẹ ipenija nla.

Awọn onimọ sọ pe ipenija nla ṣi ni ẹtẹ jẹ faraye ni paapa nilẹ Africa nibi ti ọwọja rẹ si peleke.

Akọsilẹ sọ pe nkan bi eeyan ẹgbẹrunkan le ni aadọrin eeyan lo ni aarun yi lara lagbaye.

Ninu wọn la ti ri eeyan ẹgbẹrun mọkanlelogun le diẹ to wa ni ilẹ Africa.

Nilẹ Africa orileede Naijiria ni a gbọ pe itankalẹ aarun ẹtẹ ti wọpọ julọ.

Nitori iṣọwọ bi aarun yi ṣe n ran kaakiri wọn ti wa ya ọjọ kan sọtọ lati le fi ṣe idanilẹkọ ati ipolongo aarun yi faraye gbọ.

Ọjọ taa n wi yi bọ si ọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Kini ọdun.

Bi ẹtẹ se n tan kaakiri

Awọn onimọ sọ pe aarun yi a maa ran lati ara eeyan kan omii latari pe ẹni to ba ni aarun naa le fọnka nipa ikọ, sinsin tabi mimi.

Amọ awọn onimọ yi sọ pe a maa pẹ ki aarun ẹtẹ to foju han.

Bẹẹ naa ni wọn fi to wa leti pe ti wọn ba tete ṣe ayẹwo aarun yi, ẹni to ba ni lara le gba itọju ti wọn yoo si ri wo san.

Lara awọn apẹrẹ afihan aarun yi ni piapa awọ ara ati oju da gẹgẹ bi Dokita Ibrahim Aliyu Umar ti o jẹ onimọ to n mojuto ikọ feere ati ẹtẹ ni Naijiria ṣe ṣalaye fun BBC.

O ni tori pe ẹtẹ kii ran kaakiri ni kiakia ni ko jẹ ki ọpọ eeyan mọ nipa o ṣe n tan ka.

O ni ti eeyan ba ri ọkan ninu awọn apẹrẹ aarun yi, ko tara lọ si ile iwosan lọ ṣe ayẹwo lati le mọ boya o ti ko aarun yi.

O ni eyi tun ṣe pataki lati dena kiko aaarun yi ran awọn ẹlomiran layika rẹ tabi lagbegbe to wa.

Ipinlẹ Kano jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ to n koju itankalẹ aarun yi.

Nibẹ awọn to ni aarun yi ti n ke gbajare lori aisi itọju to peye ni paapa lasiko yi to ṣe pe aarun naa ko kasẹ nilẹ tan lawujọ wọn.

Awọn alaisan kan ti BBC ba sọrọ ni ile iwosan Bela ni Kano sọ fun BBC pe oju awọn n ri to kawọn to ri itọju gba.

Awọn alaṣẹ sọ pe awọn n pese itọju ọfẹ bẹẹ si ni atunṣe n waye ni ile iwosan naa.

Kọmisọnna feto ilera nipinlẹ Kano, Dokitra Abubakar Labaran Yusuf sọ pe ''A ti fẹ ẹ pari atunṣe ile iwosan ti a o si fi ina si iyara kọọkn.Gomina wa n pese oogun ọfẹ ati ounjẹ fawọn to ni aarun yi lara''

Amọ awọn taa ba sọrọ s pe awọn ko ri itọju ọfẹ gba bi tatẹyinwa.

''Ko si itọju.Wn kii pin gbogbo nkan ti wọn ba gbe wa fun gbogbo wa''

Alaye ree ti ọkan ninu awọn to ni aarun ẹtẹ yi sọ fun BBC.

Ẹlomiran toun naa ni aarun yi sọ pe ''A kii ri oogun gba bi ti tẹlẹ mọ.Wọn kọ oogun ẹgbẹrun mejila Nair kan fun mi.Mi o le ra tori pe mi o lowo lati ra''

Iroyin to gbode nip aarun yi ni pe eeyn a maa ko lara obi rẹ ni.

Lootọ lawọn mii a maa ko lara obi wọn ṣugbọn ko ri bẹ ni gbogbo igba.

Aarun ẹtẹ a maa ṣakoba fun ọwọ eeyan ti onitọhun ko si ni le gba nkan mu daada tori akoba ti aarun yi ti ṣe fun iṣan to le jẹ ki eeyan di nkan mu daada.