Wo àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa àṣẹ wàá tí Makinde pa lórí kíkó ohun èlò ìbúgbàmù pamọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Facebook/OfficialSeyiMakinde
Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti buwọlu aṣẹ waa kan to da lori kiko nkan ibugbamu tabi nkan to le ṣe akoba pamọ.
Ni ile ijọba ni Makinde ti buwọlu aṣẹ waa yi nibi ayẹyẹ ranpẹ kan.
Aṣẹ waa yi to n waye lẹyin iṣẹlẹ ibugbamu to ṣakoba fun ẹmi ati dukia ni ipinlẹ naa.
Lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kini ni ibugbamu kan dahun ni agbegbe Bodija ni Ibadan ti awọn eeyan marun un si padanu ẹmi wọn.
Eeyan mẹtadinlọgọrin farapa ti aimọye dukia si farakasa ninu ibugbami yi.
Makinde sọ pe gbigbe aṣẹ waa yi kalẹ yoo daabo bo araalu nipa awọn nkan to le mu akoba wa ti yoo si tun dena ki iru iṣẹlẹ Bodija ma ba waye.
Ki lo rọ mọ aṣẹ waa yi ti Makinde buwọlu?
Yoruba bọ wọn ni ibi ti ko ba ti si ofin ko le si ijiya nibẹ.
Ofin to rọ mọ aṣẹ waa yi gẹgẹ bi Gomina naa ṣe ṣalaye kọkọ mọ riri fifi to ijọba leti ti eeyan ba fẹ ko nkan oloro sile yala ọlọdani tabi oni ileeṣẹ.
Loju opo rẹ ni Facebook ti Makinde fi alaye si lori aṣẹ waa yi, o ni ''ẹnikẹni to ba ni awọn nkan oloro yi lọwọ ni ipinlẹ Oyo gbọdọ fi to awọn alaṣẹ leti laarin wakati mejilelaadọrin ti aṣẹ yi ba fidi mulẹ''
Ohun ti eleyi yi tunmọ si ni pe ẹni to ko nkan to le ṣakoba sile ti ko si fi to ijọba leti ṣaaju ki aṣẹ waa yi to mulẹ gbọdọ tọ ijọba lọ lati fi to awọn alaṣẹ leti.
Ni ti tawọn to ba wa ṣẹṣẹ n ko awọn nkan yi si ipamọ, anfaani wakati mẹrinlelogun pere ni ijọba fun wọn lanfaani lati fi to awọn alaṣẹ leti.
Ki wa ni ijiya to wa fun ẹni ti ko ba ṣe bẹẹ?
Ọrọ ko pọ pupọ lori ijiya to tẹle aṣẹ waa yi.
Ni ṣoki ohun ti Gomina Makinde sọ ni pe kikọ lati tẹle ilana aṣẹ waa yi yoo ja si pe onitọhun tapa si ofin ni.
O ni ''labẹ abala kejidinlogoji iwe ofin ọdaran ipinlẹ Oyo ọdun 2000 ijiya yoo wa fun ẹnikẹni to ba keti ikun si ofin yi''
Ko sọ iru ijiya tii ṣe yala boya ẹni naa yoo ṣẹwọn ni tabi ti yoo san owo itanran.












