Ẹ kó àwọn ilé ìjọsìn, ilé ijó kúrò láàárín ilé táwọn èèyàn ń gbé láàárín oṣù kan, bíbẹ́ẹ̀kọ́... Ìjọba Eko ṣèkìlọ̀

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti fún àwọn onílé ìgbé tí wọ́n sọ ilé wọn di ilé ìjọsìn, ilé ijó tàbí ilé ọtí láì gba àṣẹ láti ṣe àyípadà bẹ́ẹ̀ ní gbèdéke oṣù kan láti dá ilé wọn padà sí ohun tó wà fún gan.
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ilé ìgbé ní ìpínlẹ̀ Eko, Gbolahan Owoduuni Oki ní gbogbo àwọn ilé tí wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan tó yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n là á kalẹ̀ fún ni ọ̀rọ̀ náà bá wí.
Oki ní ìgbésẹ̀ náà wáyé láti mú àtúntò bá bí ó ṣe yẹ kí ilé ìgbé rí ní ìpínlẹ̀ Eko pàápàá bí àwọn kan ṣe ń tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀ nípa sísọ àwọn ilé ìgbé di ilé ijó, ilé ìjọsìn àtàwọn nǹkan míì rí, tí wọ́n sì ń da òmí àláfíà àwọn àdúgbò wọn rú.
Ó wóye pé ìdí tí àwọn tún fi gbé òfin náà kalẹ̀ ni bí àwọn ènìyàn tó ń gbé ní àwọn àdúgbò tí àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ wà ṣe ń kọminú lórí ètò ààbò wọn pàápàá bí àwọn ilé ìjọsìn àti ilé ijó bẹ́ẹ̀ kò ṣe ń tẹ̀lé ìlànà tí wọ́n fi ń gbé àwọn ilé bẹ́ẹ̀ kalẹ̀.
Ó fi kun pé gbogbo àwọn tó ni àwọn ilé tí wọ́n ti sọ di mọ́ṣáláṣí, ṣọ́ọ̀ṣì, ilé ijó tàbí ilé ọtí láì gba àṣẹ ni láti ri dájú pé wọ́n ṣàtúnṣe sí èyí kí ọgbọ̀n ọjọ́ náà tó pé.
O ṣèkìlọ̀ pé tí àwọn onílé yìí kò bá ri dájú pé wọ́n ṣe àtúnṣe sí àwọn ilé náà, àwọn máa da àwọn ilé náà wó palẹ̀.
“Ìgbà ìkẹyìn rèé tí à ń ṣèkìlọ̀ fún àwọn tí wọ́n ti sọ ilé ìgbé di nǹkan mìíràn yàtọ̀ sí ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ tàbí kí a wó àwọn ilé náà.”
Oki tẹ̀síwájú pé iléeṣẹ́ àwọn ti ṣáájú ṣèkìlọ̀ fún àwọn onílé yìí tẹ́lẹ̀, tí ìkìlọ̀ tí àwọn sì ń ṣe lásìkò yìí sì jẹ́ ìkìlọ̀ ìgbẹ̀yìn kí àwọn tó máa gbé ìgbésẹ̀ láti fìyà jẹ àwọn tó bá rúfin.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé àwọn agbègbè tí àwọn nǹkan báyìí ti ń wáyé ni wọ́n kọ̀wé sí ìjọba láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí ìpalára tí àwọn ilé ìgbé bẹ́ẹ̀ ń kó bá wọn.















