ASP ọlọ́pàá fara gbọta, ajínigbé yìnbọn pa ọlọ́pàá kan àti ẹbí àwọn èèyàn tí wọ́n gbé l'Abuja

Oríṣun àwòrán, @NPF
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe ọga ọlọpaa ẹkun Bwari niluu Abuja nibi tawọn ajinigbe ti gbe baba ati ọmọ mẹfa lọ, ASP Audu Mohammed, si n gba itọju lọwọ nile iwosan lara to fara gbọta awọn ajinigbe.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi, lofidi ọrọ yi mulẹ loju opo X rẹ.
Adejobi ṣalaye pe ASP Mohammed wa lara awọn ọlọpaa to lọ si ibi ti wọn ti ji awọn eeyan gbe lọ ni Bwari niluu Abuja lọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2024 yii.
Adejobi ọlọpaa naa farapa gan an lẹyin to fara gbọta awọn ajinigbe tan, amọ, o ti n gbadun diẹ diẹ dayii.
''O ṣeni laanu pe ọlọpaa sajẹnti Ezekiel Emmanuel padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu ọhun ati buọda baba awọn eeyan ti wọn jigbe to tẹ le awọn ọlọpaa lọ sibi tawọn ajinigbe naa wa.
A gbadura pe ki Eledua tẹ wọn si afẹfẹ rere.
Ara awọn ewu to wa ninu isẹ wa gẹgẹ bi ọlọpaa niyi.
A nilo atailẹyin ati adura awọn araalu lati le ja ogun ti a n ja pẹlu awọn ọdaran oniṣẹ-ibi ni Naijiria ni ajaye.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ni ọjọ keji ọdun oṣu Kinni ọdun 2024 yii ni awọn ajinigbe yabo ile ọkunrin kan lagbegbe Bwari l’Abuja nibi ti wọn gbe ọkunrin naa atai ọmọ rẹ mẹfa lọ.
Ọrọ bẹyin yọ nigba ti awọn ajinigbe ọhun ṣekepa ọkan lara awọn ọmọ naa tori ai ri owo gọbọi tawọn ajinigbe n beere san.
Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu owo naira ni wọn sọ pe awọn yoo gba kawọn to tu wọn silẹ.
Eyi gan an lo jẹ kawọn ajinigbe naa fi baba silẹ ki o le wa owo lọ fun itusilẹ awọn ọmọ rẹ.
Airowo ọkunrin yii lo jẹ ki ọpọ eeyan lori ayelujara bẹrẹ si ni beere fun iranwọ owo fun baba awọn ọmọ yii ki awọn ajinigbe ba le fun awọn ọmọ rẹ toku ni ominira.
Lara awọn to dasi ọrọ naa lori ayelujara ni minisita eto ibaraẹnisọrọ tẹlẹ, Ọmọwe Ali Pantami.
Ọmọwe Pantami kede pe buọda oun ati ọrẹ oun kan gbe adọta miliọnu kalẹ fun itusilẹ awọn ọmọ naa.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja, pada kede pe awọn ti doola awọn eeyan kan to wa ni ahamọ ajinigbe, bo tilẹ jẹ pe ẹbi awọn ọmọbinrin ti wọn ji gbe ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lawọn san gẹgẹ owo ransọọmu.
Ninu ikede to fi sita lori ayelujara X, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Abuja, SP Josephine Adeh, sọ pe ni nnkan bi aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Abamẹta, ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni wọn doola wọn.















