Kílódé tí Makinde àti Atiku ń tahùn sí ara wọn lórí ọ̀rọ̀ ìbúgbàmù Ibadan?

Aworan Seyi Makinde ati Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde/Facebook

Lẹyin ibugbamu to waye niluu Ibadan ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, ọkanojọkan awọn eekan ilu, aṣoju ijọba ati oloṣelu lo ti ṣe abẹwo si agbegbe Adeyi, Bodija nibi ti ibugbamu naa ti fi ọpọ ẹmi ṣofo, ti o si ba ọpọ dukia jẹ.

Oloṣelu to ṣe abẹwo si ibi iṣẹlẹ naa gbẹyin lọjọ Aje ni Peter Obi, ti o jẹ oludije si ipo aarẹ orilẹede Naijiria ninu eto idibo aarẹ ọdun 2023.

Lasiko ti Obi ṣe abẹwo si ofiisi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde lati kẹdun lori iṣẹlẹ aburu naa, Makinde dupẹ lọwọ Obi fun abẹwo naa

Bẹẹ gẹgẹ lo ṣe n fi ọrọ sita wi pe igbakeji aarẹ tẹlẹri lorilẹede yii, ti o tun jẹ oludije si ipo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo to kọja lọ, Atiku Abubakar ko tii ba oun kẹdun lori ibugbamu naa.

Kini Makinde tun sọ?

Makinde sọ fun Obi pe, "mo dupẹ pe o wa si ipinlẹ wa lati ba wa kẹdun lori ibugbamu to ṣẹlẹ.

Aarẹ orilẹede yii ti kan si wa gẹgẹ bi iwọ naa ṣe fi ara han yii, ṣugbọn oludijẹ si ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu mi (Atiku) ko pe mi, bẹẹ si ni ko fi atẹjiṣẹ ranṣẹ".

"Mo n sọ eleyii ni gbangba nitori o yẹ ki awọn adari wa maa fi akoko silẹ fun eto oṣelu ati ikaanu ọmọniyan".

Makinde ni iṣe iwadii ṣi n tẹsiwaju lati ṣe awari ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ laabi naa. O fi kun ọrọ rẹ wi pe awa eeyan kan to n wa kusa lọna aitọ lo ko awọn ado oloro ti wọn n lo wa adugbo ti awọn eeyan n gbe.

Atiku náà dáa padà fun Makinde?

Ki ohun ti Makinde fi ranṣẹ si Atiku to tutu ni igbakeji aarẹ tẹlẹri naa ti fesi pada.

Alamọran pataki fun Atiku lori igbohunsafẹfẹ, Paul Ibe ṣe akojọpọ ọrọ ti Atiku fi lede fun awọn oniroyin.

Atiku ni ko si otitọ ọrọ ninu ẹsun ti Makinde fi kan oun nipa ibugbamu to ṣẹlẹ niluu Ibadan, nitori ki iṣẹlẹ naa to pe wakati mẹrinlelogun ni oun ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ijọba ati awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.

Atiku fi kun ọrọ rẹ wi pe boya nitori ọwọ Makinde to di lasiko iṣẹlẹ pajawiri naa ni ko fi ṣe akiyesi ọrọ ibanikẹdun ti oun fi ranṣẹ lẹyin iṣẹlẹ naa.

Atẹjade naa tọka rẹ ni pato wi pe lọjọ kẹtadinlogun oṣu kinni ọdun yii ni oun fi ọrọ lede lori ikanni ayelujara lati ba awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ kẹdun lori iṣẹlẹ naa.