Travel Ban: Nnkán marun tó yẹ kí o mọ nípa àṣẹ wàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni oṣu kinni ọdun 1868,Aarẹ orileede Amerika Abraham Lincoln, pasẹ waa kan lati mu iyipada ba ipo awọn ẹru alawọ-dudu to le ni miliọnu mẹta, labẹ ofin ni awọn ipinlẹ mẹwa lamẹrika.
Asẹ itusilẹ rẹ ọhun ko jẹ ofin alagbada tabi ofin ologun, sugbọn aṣẹ waa ni wọn pee, ti itunmọ rẹ lede Gẹẹsi a si maa jẹ Executive Order.
Lamerika ati ni orileede Naijiria ti isejọba awa ara wa nipase lilo Aarẹ gẹgẹ bi olori ijọb, aye wa fun Aarẹ lati lo agbara aṣẹ waa.
Bakan naa, lai pẹ yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari gbe aṣẹ waa, ẹlẹkẹfa jade eleyi ti ko faaye gba ẹnikẹni ti o ba ni dukia to le ni aadọta miliọnu Naira, ti ijọba si n wadi rẹ fun ẹsun iwa ibajẹ, lati raaye fi orilẹ-ede Naijiria silẹ, titi ti wọn yoo fi gbe igbesẹ to tọ lori ọrọ wọn.
N ṣe ni awuyewuye n waye lori igbese naa, eyi kii si se igba akọkọ ti Aarẹ Buhari yoo pa iru aṣe yii ṣugbọn o da bi ẹni wi pe, oun ti àṣẹ wàá je gan, ko yẹ ọpọ eeyan.
E jẹ ki a jọ salaye rẹ ko ye wa yegeyege.
Asẹ wa kii se ofin ṣugbọn o lagbara ti ofin naa ni.
Ki a to lee ṣofin kankan, a gbodo tele awọn ilana ti ofin la kalẹ.
Ilana wọnyi a maa gba asiko ti o seese ki o ma le jẹ ki ofin naa ba nnkan ti wọn fẹ lo fun.
Fun idi ẹy,i ni wọn fii fun Aarẹ ni agbara lati pasẹ wa lai beere iyọnda lọdọ awọn asofin.
Ti Aarẹ ba gbe igbese yi, aṣẹ naa ti di ofin, to si di dandan ki awọn ara ilu tele.

Oríṣun àwòrán, @Mbuhari
Àṣẹ wàá gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ofin ilu
Ohun pataki to yẹ ki a mọ nipa asẹ waa ni pe, awọn ile ẹjọ a ma se agbeyẹwo aṣẹ wa ti Aarẹ ba pa loorekoore.
Koda awọn asofin le tapa si tabi fagile aṣẹ wa ti Aarẹ ba pa, ti wọn ba ri wi pe Aarẹ fẹ lo ofin ọhun nilokulo tabi ti ofin naa ko le ṣe anfaani fun ara ilu.
Sugbọn Aarẹ gbodo buwọlu ofin tuntun naa ki o to le parọ àṣẹ wàá, to wa nilẹ tele.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Fun idi eyi, aṣẹ wa a ma wo ibi ti kudie kudie ba wa ninu isejọba,lọna ati mu agbega ba agbọn yii.
Ti àṣẹ wàá ko ba tẹ Aarẹ tuntun miran lọrun,o le paarẹ
Àṣẹ wàá le jẹ lilo fun ọdun kan, ọdun mẹwa tabi titi lailai, lopin igba ti Aarẹ mii ko ba ti fagile.
Gẹgẹ bi agbekalẹ ati ilana lilo agbara yii labẹ iwe ofin Naijiria, Aarẹ tuntun le ni oun fẹ yi àṣẹ wàá pada ti yoo si fi omiran rọpo rẹ tabi ko tilẹ ma lo mọ rara.
Apẹrẹ iru rẹ kan to waye ni Naijiria ni ti aṣẹ waa ti Aarẹ Obasanjọ pa, lati sọ ọjọ kọkandilọgbọn osu kaarun di ayajọ ọjọ oselu tiwantiwa ni Naijiria.
Lai pe yi ni Aarẹ Buhari yi aṣẹ yi pada, si ọjọ Kejila osu Kefa, June 12, di ọjọ ayajọ ijọ oselu awa ara wa ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àṣẹ wàá melo ni aarẹ le pa?
Iye àṣẹ wàá ti Aarẹ le pa ko niye.
Lorileede Amerika, a ti ri Aarẹ to pa àṣẹ wàá to to ẹgbẹrun meta, ti awọn miran ko si buwọlu àṣẹ wàá kankan ti saa wọn fi pari saa wọn.
Ni Naijiria Aarẹ Muhammadu Buhari lo tii pasẹ waa to poju, tii se mẹfa.
Nigba Aarẹ Obasanjọ ati Aarẹ Goodluck Jonathan, awọn naa pa awọn asẹ waa kan sugbọn ko to ti iye Aarẹ Buhari.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Aarẹ a ma lo àṣẹ wàá lati fi se ẹkunrẹrẹ alaye nipa ofin
Nigba miran alaye nipa ofin le ma ye awọn eeyan daada tabi ko se wi pe o sokunkun si awọn eeyan.
Lati le mu alaye to ye kooro wa nipa ofin bẹ, Aarẹ le pase wa ti yoo mu ekunrẹrẹ alaye wa nipa irufẹ ona ti wn le lo ofin naa tabi alaye nnkan pato ti wọn tori rẹ sofin naa.
















