Kí ló dé tí Makinde fi ní kí Ọba Àlàyé lọ rọọ́kún nílé fún ìgbà díẹ̀?

Aworan Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ni ki Ọba alaye kan lọ rọọkun nile fun igba diẹ fun ẹsun pe o ni ibaṣepọ ikọkọ pẹlu awọn to n wa kusa lọna aìtọ.

Ijọba ipinlẹ Oyo, ninu atẹjade kan ti wọn fi sọwọ si awọn akọroyin lati ọwọ kọmisana fun ẹka iroyin, Dotun Oyelade ni Gomina Seyi Makinde lo gbe aṣẹ naa kalẹ pe ki Ọba Gbologade Babalola (Gbadewolu I), Onido ti ilu Ido lọ rọọkun ni ile.

Oyelade ni ijọba ipinlẹ Oyo gbe igbesẹ fifofin de Ọba alade yii lati fi ohun agbara ransẹ si awọn ọdaran pẹlu awọn janduku to n da agbegebe ipinlẹ Oyo laamu.

Gẹgẹ bii Kọmisana ṣe salaye, Gomina fofin de Onido ti Ido nitori iwadi fihan pe o ni nnkan se pẹlu awọn to n wa kusa lọna aìtọ ni ijọba ibilẹ naa.

“Ninu igbiyanju lati gbe ogun ti iwa ibajẹ ati awọn ọdaran lati kuro ni ipinlẹ wa, a n fi eyi sọwọ si irufẹ awọn eeyan bayii pe ọwọ palaba wọn yoo sẹgi, ti wọn yoo si foju ba ofin laipẹ.”

Oludaramọran fun Gomina lori iroyin, Sulaimon Olanrewaju ni Ọjọ kinni oṣu keji ni Gomina buwọlu pe ki wọn fi fofin de Oba alade naa.

Ninu atẹjade ti Kọmisana fun ijọba ibilẹ ati ifinijẹoye nipinlẹ, Hon Olusegun Olayiwola fi lede, Ijọba palasẹ fun Ọba Babalola lati juwọ gbogbo dukia ijọba to wa lọwọ rẹ silẹ ni ọfisi Alaga ijọba ibilẹ Ido.

“Mo n fi to yin leti pe Gomina ipinlẹ Oyo, pẹlu ilana ti ofin gbe kalẹ to jẹ ti ọdun 2000, buwọlu fi fofin de Oba, Onido ti ilu Ido ni agbegbe ijọba ibilẹ Ido nipinlẹ Oyo.

Eyi lo n waye lẹyin ọsẹ mẹta ti isẹlẹ ibugbamu waye ni agbegbe Adeyi Bodija niluu Ibadan,

Isẹlẹ ọhun lo mu ẹmi eeyan marun un, ti ọpọ eeyan si farapa yanayana. Ọpọ dukia lo bajẹ lasiko ibugbamu naa.