Àjọ INEC dá ètò ìdìbò dúró ní àwọn ìpínlẹ̀ kan

Aworan Alaga INEC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ti kede sita pe awọn ti da atundi eto idibo to n lọwọ ni ipinlẹ Kano, Enugu ati Akwa Ibom duro.

INEC kede ọrọ yii ninu ayẹjade ti wọn fi sita fun awọn akọroyin pe awọn gbe awọn igbesẹ yii nitori bi awọn osisẹ ajọ naa ṣe ko sọwọ awọn ajinigbe, ti awọn janduku kan si tun ji eroja eto idibo gbe lọ ni awọn ipinlẹ naa.

Atẹjade naa ni awọn agbegbe ti ọrọ kan naa ni agbegbe meji ti eto idibo ti n waye ni Akwa Ibom ni ijọba ibilẹ Ikono/Ini, ni bi ti awọn janduku kan ti kọlu awọn osisẹ ajọ eleto idibo.

Nipinlẹ Enugu, INEC ni iwe esi idibo ti jade sita saaju ki eto idibo to waye ni agbegbe mẹjọ ti eto idibo ti fẹ waye.

Bakan naa ni agbegbe Kunchi ati Tsanyawa, INEC ni ija bẹ silẹ ni ibudo eto idibo mẹwaa, ti awọn janduku kan si ba ọpọ dukia to jẹ ti eleto idibo jẹ.

INEC ni awọn gbe aṣẹ naa kalẹ ni ilana pẹlu iwe ofin to dirọ mọ pe ki awọn da eto idibo duro ni iru asiko bayii.

Ajọ INEC ti wa kesi awọn ẹlẹsọ alabo lati se iwadi si ohun to waye naa, ki wọn si fi ọwọ ofin mu awọn janduku to se ikọlu si awọn osisẹ INEC ni awọn ipinlẹ naa.